Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 5:10-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ọgbà-àjàrà sarè oko mẹwàá yóò múìkòkò wáìnì kan wá,nígbà tí òṣùwọ̀n hómérì kan yóò múagbọ̀n irúgbin kan wá.”

11. Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìdení kùtùkùtù òwúrọ̀láti lépa ọtí líle,tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì.

12. Wọ́n ní hápù àti láà níbi àṣè wọn,tamborínìn òun fèrè àti wáìnì,ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,kò sí ìbọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

13. Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóòlọ sí ìgbèkùnnítorí òye kò sí fún wọn,ebi ni yóò pa àwọn bọ̀rọ̀kìnní wọn kú;ẹgbàágbèje wọn ni òrùgbẹyóò sì gbẹ.

14. Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi,ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada,nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sípẹ̀lú ọlá àti ògo wọn.

15. Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀àti ọmọnìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀.

16. Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀,Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀.

17. Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn,àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀.

18. Ègbé ni fún àwọn tí ń fi okùn,àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fí okùn kẹ́kẹ́ ẹ̀sìn fa ìkà,

19. sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá,jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè ríi,jẹ́ kí ó súnmọ́ bíjẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì kí ó dé,kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.”

20. Ègbé ni fún àwọn tí ń pe ibi ní rere, àti rere ní ibi,tí ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkunkun,tí ń fi ìkorò ṣe adùn àti adùn ṣe ìkorò.

21. Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọntí wọ́n já fáfá lójú ara wọn.

22. Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímuàti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí,

23. tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́.

24. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àkékù koríko runàti bí koríko ṣe relẹ̀ wẹ̀sì nínú iná,bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹràtí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku:nítorí pé wọ́n ti kọ òfin Olúwa àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.

25. Nítorí náà, ìbínú Olúwa gbóná mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀,ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ ṣókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀.Àwọn òkè mì tìtì,àwọn òkú sì dàbí ààtàn lójú òpópó ọ̀nà.Pẹ̀lúu gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíí kúrò,ọ̀wọ́ rẹ̀ sì gbé ṣókè síbẹ̀.

26. Ó gbé ọ̀págun ṣókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà-réré,Ó súfèé sí àwọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀.Àwọn rè é, wọ́n ti sáré

27. Kò rẹ ẹnìkankan nínú wọn, tàbí kí ó kọṣẹ̀.Ẹnikẹ́ni ò tòògbé tàbí sùn;Ìgbànú ẹnìkankan ò dẹ̀ ní ìbàdí i rẹ̀,okùn sálúbàtà kan ò já.

Ka pipe ipin Àìsáyà 5