Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 48:13-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀,àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run;nígbà tí mo pè wọ́n,gbogbo wọn dìde ṣókè papọ̀.

14. “Ẹ gbárajọ pọ̀ gbogbo yín kí ẹ sì dẹtí:Èwo nínú àwọn ère òrìṣà rẹló ti sọ nǹkan wọ̀nyí?Àkójọpọ̀ àwọn àyànfẹ́ Olúwani yóò gbé ète yìí jáde sí Bábílónì;apá rẹ̀ ni yóò dojú kọ àwọn aráa Bábílónì.

15. Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀;bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é.Èmi yóò mú un wá,òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀.

16. “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí:“Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀;ní àṣìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.”Àti ní àkókò yìí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó ti rán mi,pẹ̀lú ẹ̀mii rẹ̀.

17. Èyí ni ohun tí Olúwa wíOlùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì:“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ,tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn.

18. Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tísílẹ̀ sí àṣẹ mi,àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò,àti òdodo rẹ bí ìgbì òkun.

19. Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí i yanrìn,àwọn ọmọ yín bí i horo ọkà tí a kò lè kà tán;orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúròtàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.”

20. Fi Bábílónì sílẹ̀,sá fún àwọn ará Bábílónì,ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀kí o sì kéde rẹ̀.Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé;wí pé, “Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jákọ́bù nídè.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 48