Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 47:5-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. “Jókòó ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, lọ sínú òkùnkùn,ọmọbìnrin àwọn ará Bábílónì;a kì yóò pè ọ́ ní ọbabìnrinàwọn ilẹ̀-ọba mọ́.

6. Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mití mo sì ba ogún mi jẹ́;Mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́,Ìwọ kò sì síjú àánú wò wọ́n.Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lúní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé.

7. Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀ṣíwájú títí láé—ọba-bìnrin ayérayé!’Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsí nǹkan wọ̀nyítàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.

8. “Nísinsìn yìí, tẹ́tísílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dátí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹtí o sì ń sọ fún ara rẹ pé,‘Èmi ni, kò sì sí ẹlòmìíràn lẹ́yìn mi.Èmi kì yóò di opótàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’

9. Méjèèjì yìí ni yóò wá sóríì rẹláìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà:pípàdánù ọmọ àti dídi opó.Wọn yóò wá sóríì rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹàti àwọn èpè rẹ tí kì í ṣélẹ̀.

10. Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹó sì ti wí pé, ‘kò sí ẹni tí ó rí mi?’Ọgbọ́n àti òye rẹ ti sì ọ́ lọ́nànígbà tí o wí fún ara rẹ pé,‘Èmi ni, kò sí ẹlòmìíràn lẹ́yìn mi.’

11. Ìparun yóò dé bá ọbẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò mọ ọ̀nà láti ré e kúrò.Àjálù kan yóò ṣubú lù ọ́tí o kì yóò le è fi ètùtù ré kúrò;òfò kan tí o kò le ròtì niyóò wá lójijì sí oríì rẹ.

12. “Tẹ̀ṣíwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹàti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo,tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá.Bóyá o le è ṣàṣeyọrí,bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 47