Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 46:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bẹ́lì tẹríi rẹ̀ ba, Nébò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀;àwọn ère wọn ni àwọn ẹranko rù.Àwọn ère tí wọ́n ń rù káàkiri ti diàjàgà sí wọn lọ́rùn,ẹrù fún àwọn tí àárẹ̀ mú.

2. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì foríbalẹ̀ papọ̀;wọn kò lè gba ẹrù náà,àwọn pẹ̀lú ni a kó lọ ní ìgbèkùn.

3. “Tẹ́tí sími ìwọ ilé Jákọ́bù,Gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Ísírẹ́lì,Ìwọ tí mo ti gbérò láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún,tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ.

4. Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú oríi yínÈmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró.Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ;Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀.

5. “Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba?Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mití àwa yóò jọ farawéra?

6. Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọnwọ́n sì wọn fàdákà lórí òṣùwọ̀n;wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà,wọn sì tẹríba láti sìn ín.

Ka pipe ipin Àìsáyà 46