Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 44:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná;lóríi rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀,ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó.Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé,“Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.”

17. Nínú èyí tí ó kù ni ó ti ṣe òrìṣà, ère rẹ̀;ó forí balẹ̀ fún un, ó sì sìn ín.Ó gbàdúrà sí i, ó wí pé,“Gbà mí, ìwọ ni Ọlọ́run mi.”

18. Wọn kò mọ nǹkankan, nǹkankan kò yé wọn;a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkankan;bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkankan.

19. Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú,kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òyeláti sọ wí pé,“Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná;Mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀,Mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́.Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kannínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí?Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?”

20. Ó ń jẹ eérú, ọkàn ẹlẹ̀tàn ni ó sì í lọ́nà;òun kò lè gba ara rẹ̀ là, tàbí kí ó wí pé“Ǹjẹ́ nǹkan tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí irọ́ kọ́?”

Ka pipe ipin Àìsáyà 44