Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 43:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣùgbọ́n ní ìsinsìn yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìíẹni tí ó dá ọ, Ìwọ Jákọ́bùẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Ísírẹ́lì:“Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;Èmi ti pè ọ́ ní orúkọtèmi ni ìwọ ṣe.

2. Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,Èmi yóò wà pẹ̀lúu rẹ;àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjáwọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,kò ní jó ọ;ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.

3. Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì Olùgbàlà rẹ;Èmi fi Éjíbítì ṣe ìràpadà rẹ,Kúṣì àti Ṣébà dípò rẹ.

4. Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,àti ènìyàn dípò ẹ̀míì rẹ.

5. Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lúù rẹ;Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà oòrùn wáèmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀ oòrùn.

6. Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’àti fún gúṣù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jínjìn wáàti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—

7. ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́,tí mo dá fún ògo mi,tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”

8. Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde,tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití.

9. Gbogbo orílẹ̀ èdè kóra wọn jọàwọn ènìyàn sì kóra wọn papọ̀.Ta ni nínú wọn tó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ yìítí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀?Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wáláti fi hàn pé wọ́n tọ̀nàtó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́, tíwọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.”

10. “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí,“Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn,tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà ḿi gbọ́tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà.Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá,tàbí a ó wa rí òmìíràn lẹ́yìn mi.

11. Èmi, àní Èmi, Èmi ni Olúwa,yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 43