Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 42:9-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Kíyèsí i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé,àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé;kí wọn tó hù jádemo ti kéde rẹ̀ fún ọ.”

10. Kọ orin titun sí Olúwaìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá,ẹ̀yin tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkun, àtiohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú un wọn.

11. Jẹ́ kí ihà àti àwọn ìlúu rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn ṣókè;jẹ́ kí ibùdó ti àwọn igi kédárì ń gbé máa yọ̀.Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Ṣẹ́là kọrin fún ayọ̀;jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè.

12. Jẹ́ kí wọn fi ògo fún Olúwaàti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù.

13. Olúwa yóò rìn jáde gẹ́gẹ́ bí i ọkùnrin alágbára,gẹ́gẹ́ bí jagunjagun yóò ti gbé ohun ipá rẹ̀ ṣókè;pẹ̀lú ariwo, òun yóò ké igbe ogunòun yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀ta rẹ̀.

14. “Fún ìgbà pípẹ́ ni mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́,mo ti wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì kó ara ró.Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí,mo ṣunkún, mo sì ń mí hẹlẹ hẹlẹ.

15. Èmi yóò sọ òkè ńlá àti kékeré di ahorotí n ó sì gbẹ gbogbo ewéko rẹ̀ dànù;Èmi yóò sọ àwọn odò di erékùṣùn ó sì gbẹ àwọn adágún.

16. Èmi yóò tọ àwọn afọ́jú ní ọ̀nà tí wọn kò tí ì mọ̀,ní ipa-ọ̀nà tí ó ṣàjèjì sí wọn ni èmi yóò tọ́ wọn lọ;Èmi yóò sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájúu wọnàti ibi pálapàla ni èmi ó sọ di kíkúnná.Àwọn nǹkan tí máa ṣe nìyìí;Èmi kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

17. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà,tí wọ́n wí fún ère pé, ‘Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa,’ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú.

18. “Gbọ́, ìwọ adití,wòó, ìwọ afọ́jú, o sì rí!

19. Ta ló fọ́jú bí kò ṣe ìránṣẹ́ mi,àti odi gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí mo rán?Ta ni ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fi jìnmí,ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Olúwa?

20. Ẹ̀yin ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, ṣùgbọ́n ẹ kò ṣe àkíyèsí;etí yín yà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́ nǹkankan.”

21. Ó dùn mọ́ Olúwanítorí òdodo rẹ̀láti mú òfin rẹ lágbára àti ògo.

22. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan níyìí tí a jà lóguntí a sì kó lẹ́rú,gbogbo wọn ni ó wà nínú ọ̀gbun,tàbí tí a fi pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n.Wọ́n ti di ìkógun,láìsí ẹnìkan tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀;wọ́n ti di ìkógun,láìsí ẹni tí yóò sọ pé, “Dá wọn padà.”

23. Ta ni nínú un yín tí yóò tẹ́tí sí èyítàbí kí ó ṣe àkíyèsí gidi ní àsìkò tí ó ń bọ̀?

24. Ta ni ó fi Jákọ́bù lélẹ̀ fún ìkógun,àti Ísírẹ́lì sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí?Kì í há ṣe Olúwa ni,ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí?Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀;wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ.

25. Nítorí náà ni ó ṣe rọ̀jò ìbínú un rẹ̀ lé wọn lórí,rògbòdìyàn ogun.Èyí tí ó fi ahọ́n iná yí wọn po, síbẹ̀èdè kò yé wọn;ó jó wọn run, síbẹ̀ wọn kò fi sọ́kàn wọn rárá.

Ka pipe ipin Àìsáyà 42