Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 41:19-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀igi kédárì àti akaṣíà, mítílì àti ólífì.Èmi yóò da páínì sí inú ilẹ̀ síṣá,igi fíri àti ṣípírẹ́ṣì papọ̀

20. tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀,kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn,pé ọwọ́ Olúwa ni ó ti ṣe èyí,àti pé Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ni ó ti dá èyí.

21. “Mú ẹjọ́ wá,” ni Olúwa wí.“Tẹ́ àwọn àwíjàre rẹ sílẹ̀,” ni ọba Jákọ́bù wí

22. “Mú àwọn ère-òrìṣà rẹ wọlé láti sọ fún waohun tí yóò ṣẹlẹ̀.Sọ fún wa ohun tí àwọn nǹkan àtijọ́ jẹ́,kí àwa lè ṣe àgbéyẹ̀wò wọnkí àwa sì mọ àbájáde wọn níparí.Tàbí kí o sọ fún wa ohun tí ó ń bọ̀ wá,

23. ẹ sọ fún wa ohun ti ọjọ́ iwájú mú dáníkí àwa kí ó lè mọ̀ pé Ọlọ́run niyín.Ẹ ṣe nǹkankan, ìbáà ṣe rere tàbí búburú,tó bẹ́ẹ̀ tí àyà yóò fi fò wá tí ẹ̀rù yóò sì fi kún inú wa.

24. Ṣùgbọ́n ẹ̀yìn ko já sí nǹkankaniṣẹ́ yín ni kò sì wúlò fún ohunkóhun;ẹni tí ó yàn yín jẹ́ ẹni ìríra.

25. “Èmi ti ru ẹnìkan sókè láti àríwá, òun sì ń bọẹnìkan láti ìlà oòrùn tí ó pe orúkọ mi.Òun gun àwọn aláṣẹ mọ́lẹ̀ bí ẹni pé odò ni wọ́n,àfi bí ẹni pé amọ̀kòkò nì ti ń gún amọ̀.

26. Ta ni ó sọ èyí láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀,tí àwa kò bá fi mọ̀,tàbí ṣáájú àkókò, tí àwa kò bá fi wí pé,‘Òun sọ òtítọ́’?Ẹnikẹ́ni kò sọ nípa èyí,ẹnikẹ́ni kò sàṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀,ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.

27. Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó sọ fún Ṣíhóńì pé,‘Wò ó, àwọn nìyìí!’Mo fún Jérúsálẹ́mù ní ìránṣẹ́ ìhìn ayọ̀ kan.

28. Èmi wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan—kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó lè mú ìmọ̀ràn wá,kò sí ẹnìkan tí ó lè dáhùn nígbà tí mo bi wọ́n.

29. Kíyèsí i, irọ́ ni gbogbo wọn!Gbogbo ìṣe wọn já sí asán;àwọn ère wọn kò ṣé kò yà fúnafẹ́fẹ́ àti dàrúdàpọ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 41