Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 41:12-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀ta rẹ,ìwọ kì yóò rí wọn.Gbogbo àwọn tí ó gbógun tì ọ́yóò dàbí òfuuru gbádá.

13. Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mútí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù;Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.

14. Ìwọ má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jákọ́bù kòkòrò,Ìwọ Ísírẹ́lì kékeré,nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,”ni Olúwa wí,olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì.

15. “Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà,tuntun tí ó mú ti eyín rẹ̀ mu, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá,ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú,a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò.

16. Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú,àti ẹ̀fúùfù yóò sì gbá wọn dànùṢùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú Olúwaìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì.

17. “Àwọn talákà àti aláìní wá omi,ṣùgbọ́n kò sí;ahọ́n wọn ṣáàápá fún òrùngbẹ.Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò dá wọn lóhùn;Èmi, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

18. Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní àwọnibi gíga pọ́nyán ún,àti oríṣun omi ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀.Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi,àti ilẹ̀ tí ó ṣáàápá yóò di orísun omi.

19. Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀igi kédárì àti akaṣíà, mítílì àti ólífì.Èmi yóò da páínì sí inú ilẹ̀ síṣá,igi fíri àti ṣípírẹ́ṣì papọ̀

20. tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀,kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn,pé ọwọ́ Olúwa ni ó ti ṣe èyí,àti pé Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ni ó ti dá èyí.

21. “Mú ẹjọ́ wá,” ni Olúwa wí.“Tẹ́ àwọn àwíjàre rẹ sílẹ̀,” ni ọba Jákọ́bù wí

Ka pipe ipin Àìsáyà 41