Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 40:20-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ọkùnrin kan tí ó talákà ju kí ó lè múirú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá,wá igi tí kò le è rà.Ó wá oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú.

21. Ǹjẹ́ o kò tí ì mọ̀ìwọ kò tí ì gbọ́?A kò tí ì sọ fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá?Ìwọ kò tí ì mọ láti ìgbà ìpilẹ̀ ayé?

22. Òun jókòó lórí Ìtẹ́ ní òkè òbììrí ilẹ̀ ayé,àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata.Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà,ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé.

23. Ó sọ àwọn ọmọ ọba di aṣánàti àwọn aláṣẹ ayé yìí ni ó ti sọ dòfo.

24. Gẹ́rẹ́ tí a ti gbìn wọ́n,kété tí a gbìn wọ́n,kété tí wọ́n tita ẹ̀kan nínú ilẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ó fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n gbogbo wọn sì gbẹ,bẹ́ ni ìji-líle sì gbá wọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò.

25. “Ta ni ẹ ó fi mi wé?Tàbí ta ni ó bámi dọ́gba?” ni Ẹni-Mímọ́ wí.

26. Gbé ojú rẹ ṣókè kí o sì wo àwọn ọ̀run:Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí?Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kantí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan.Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀,ọ̀kanṣoṣo nínú wọn kò sọnù.

27. Èéṣe tí o fi sọ, Ìwọ Jákọ́bùàti tí o ṣàròyé, Ìwọ Ísírẹ́lì;“Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú Olúwa;ìṣe mi ni a kò kọbi ara síláti ọwọ́ Ọlọ́run mi”?

28. Ìwọ kò tí ì mọ̀?Ìwọ kò tí ì gbọ́? Olúwa òun ni Ọlọ́run ayérayé,Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀-ayé.Òun kì yóò ṣàárẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sì,àti ìmọ̀ rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdiwọ̀n rẹ̀.

29. Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀ó sì fi kún agbára àwọn aláàárẹ̀.

30. Àní àwọn ọ̀dọ́ ń rẹ̀wẹ̀sì, ó ń rẹ̀ wọ́n,àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú;

31. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwayóò tún agbára wọn ṣe.Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì;wọn yóò ṣáré àárẹ̀ kò ní mú wọn,wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 40