Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 40:16-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Lẹ́bánónì kò tó fún pẹpẹ iná,tàbí kí àwọn ẹranko rẹ̀ kí ó tó fún ẹbọ sísun.

17. Níwájúù rẹ ni gbogbo orílẹ̀ èdè dàbí ohun tí kò sí;gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlòtí kò tó ohun tí kò sí.

18. Ta ni nígbà náà tí ìwọ yóò fi Ọlọ́run wé?Ère wo ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé rẹ̀?

19. Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á,ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ótí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un.

20. Ọkùnrin kan tí ó talákà ju kí ó lè múirú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá,wá igi tí kò le è rà.Ó wá oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú.

21. Ǹjẹ́ o kò tí ì mọ̀ìwọ kò tí ì gbọ́?A kò tí ì sọ fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá?Ìwọ kò tí ì mọ láti ìgbà ìpilẹ̀ ayé?

22. Òun jókòó lórí Ìtẹ́ ní òkè òbììrí ilẹ̀ ayé,àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata.Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà,ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé.

23. Ó sọ àwọn ọmọ ọba di aṣánàti àwọn aláṣẹ ayé yìí ni ó ti sọ dòfo.

Ka pipe ipin Àìsáyà 40