Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 39:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Àsìkò ń bọ̀ nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin rẹ, àti ohun gbogbo tí àwọn baba rẹ ti kó jọ títí di ọjọ́ òní yóò di kíkólọ sí Bábílónì. Ohun kankan kò ní ṣẹ́kù ni Olúwa wí.

7. Àti díẹ̀ nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ, àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara rẹ tí a ó bí fún ọ ni a ó kó lọ, wọn yóò sì di ìwọ̀fà nínú ààfin ọba Bábílónì.”

8. “Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ dára,” ni èsì Heṣekáyà. Nítorí ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Àlàáfíà àti ààbò yóò wà ní Ìgbà ayé tèmi.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 39