Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 38:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Èmi yóò sì gba ìwọ àti ìlú yìí sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọba Áṣíríà. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí.

7. “ ‘Èyí yìí ni àmì tí Olúwa fún ọ láti fi hàn wí pé Olúwa yóò mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ:

8. Èmi yóò mú òjìji òòrùn kí ó padà ṣẹ́yìn ní ìsísẹ̀ mẹ́wàá nínú èyí tí ó fi ṣọ̀kalẹ̀ ní ibi àtẹ̀gùn ti Áhásì.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni òòrùn padà ṣẹ́yìn ní ìsíṣẹ̀ mẹ́wàá sí ibi tí ó ti dé tẹ́lẹ̀.

9. Ìwé tí Heṣekáyà ọba Júdà kọ lẹ́yìn àìṣàn rẹ̀ nígbà tí ó ti gbádùn tán:

10. Èmi wí pé, “Ní àárin gbùngbùn ọjọ́ ayé mièmi ó ha kọjá lọ ní ibodè ikúkí a sì dùn mí ní àwọn ọdún mi tí ó ṣẹ́kù?”

11. Èmi wí pé, “Èmi kì yóò lè tún rí Olúwa mọ́,àni Olúwa, ní ilẹ̀ àwọn alààyè;èmi kì yóò lè síjú wo ọmọnìyàn mọ́,tàbí kí n wà pẹ̀lú àwọn tí ó sì ńgbe orílẹ̀ ayé báyìí.

12. Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn, ilé mini a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ọ̀ mi.Gẹ́gẹ́ bí ahunsọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà;ọ̀ṣán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi.

13. Èmi fi ṣùúrù dúró títí di àfẹ̀mọ́jú,ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ó ti fọ́ gbogbo egungun mi;ọ̀ṣán àti òru ni ìwọ fi ṣe òpin mi.

14. Èmi sunkún gẹ́gẹ́ bí ìṣáré tàbí ìgún,Èmi pohùnréré gẹ́gẹ́ bí aṣọ̀fọ̀ àdàbà.Ojú mi rẹ̀wẹ̀sì gẹ́gẹ́ bí mo ti ń wo àwọn ọ̀run.Ìdààmú bámi; Ìwọ Olúwa, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi!”

Ka pipe ipin Àìsáyà 38