Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 33:3-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá,nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀ èdè fọ́nká.

4. Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀ èdè ni a kórègẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú;gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn bọ́ lù ú.

5. A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga;Òun yóò kún Ṣíhónì pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.

6. Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀;ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí.

7. Wò ó, àwọn onígboyà ọkùnrin wọn pohùnréréẹkún ní òpópónà;àwọn ikọ̀ àlàáfíà ṣunkún kíkorò.

8. Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣátì,kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nàA ti ba àdéhùn jẹ́,a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí,a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni.

9. Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù,ojú ti Lẹ́bánónì ó sì ṣáṢárónì sì dàbí aginjù,àti Báṣánì òun Kámẹ́lì rẹ àwọn èwe wọn.

10. “Ní ìsinsìn yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí.“Ní ìsinsìn yìí ni a ó gbé mi ga,ní ìsinsìn yìí ni a ó gbé mi sókè.

11. Ìwọ lóyún fùfùléèléè,o sì bí koríko;èémí rẹ iná ni tí ó ń jó ọ run.

12. A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú;bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”

13. Ìwọ tí ó wà lọ́nà jínjìn, gbọ́ ohuntí mo ti ṣe;Ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!

Ka pipe ipin Àìsáyà 33