Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 33:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ègbé ni fún ọ, ìwọ apanirun,ìwọ tí a kò tí ì pa ọ́ run!Ègbé ni fún ọ, ìwọ ọ̀dàlẹ̀,ìwọ tí a kò tí ì dà ọ́!Nígbà tí o bá dẹ́kun à ń panirun;a ó pa ìwọ náà run,nígbà tí o bá dẹ́kun à ń dani,a ó da ìwọ náà.

2. Olúwa ṣàánú fún waàwa ń ṣàfẹ́ríi rẹ.Má a jẹ́ agbára wa ní òròòwúrọ̀ìgbàlà wa ní àsìkò ìpọ́njú.

3. Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá,nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀ èdè fọ́nká.

4. Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀ èdè ni a kórègẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú;gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn bọ́ lù ú.

5. A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga;Òun yóò kún Ṣíhónì pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.

6. Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀;ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí.

7. Wò ó, àwọn onígboyà ọkùnrin wọn pohùnréréẹkún ní òpópónà;àwọn ikọ̀ àlàáfíà ṣunkún kíkorò.

8. Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣátì,kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nàA ti ba àdéhùn jẹ́,a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí,a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni.

9. Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù,ojú ti Lẹ́bánónì ó sì ṣáṢárónì sì dàbí aginjù,àti Báṣánì òun Kámẹ́lì rẹ àwọn èwe wọn.

10. “Ní ìsinsìn yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí.“Ní ìsinsìn yìí ni a ó gbé mi ga,ní ìsinsìn yìí ni a ó gbé mi sókè.

Ka pipe ipin Àìsáyà 33