Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 3:11-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ẹ̀gbé ni fún aṣebi! Ìparun wà lóríi wọnA ó sì san èrè iṣẹ́ tí ọwọ́ wọn ti ṣe fún wọn.

12. Àwọn ọ̀dọ̀mọdé ni o ń pọ́n àwọn ènìyàn mi lójúàwọn obìnrin ń jọba lé wọn lórí.Áà! Ènìyàn mi àwọn afinimọ̀nà yín ti sìyín lọ́nà,wọn sì mú yín kúrò ní ipa ọ̀nà yín.

13. Olúwa bọ sí ipo rẹ̀ ní ìtẹ́ ìdájọ́Ó dìde láti dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́.

14. Olúwa dojú ẹjọ́ kọàwọn alàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀.“Ẹyin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi,ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín.

15. Kín ni èro yín láti máa run àwọnènìyàn mi túútúútí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ?”ni Olúwa wí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

16. Olúwa wí pé,“Àwọn obìnrin Ṣíónì jẹ́ agbéraga,wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn,tí wọn ń fojú pe ọkùnrin,tí wọn ń sọ̀dí bí wọn ti ń yan lọpẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjan wọnjan lọ́rùn ẹṣẹ̀ wọn.

17. Nítorí náà Olúwa yóò mú egbòwá sórí àwọn obìnrin Ṣíónì, Olúwa yóò sì pá wọn ní agbárí.”

18. Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti ìgbàrí àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá

19. gbogbo yẹtí, ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú,

20. gbogbo gèlè ìwégbà ọrùn ẹ̀ṣẹ̀ àti àyà, àwọn ìgo tùràrí àti òògùn,

21. òrùka ọwọ́ àti ti imú,

22. àwọn àtàtà aṣọ, àwọ̀lékè, agbádá àti àpamọ́wọ́,

23. Díńgí wọn, aṣọ funfun nigínnigín ìbòrí àti ìbòjú.

24. Dípò òórùn dídùn, òórún búbubú ni yóò wá,okùn ni yóò wà dípò àmùrè,orí pípá ni yóò dípò ìrun ti a ṣe ní ọ̀ṣọ́aṣọ ọ̀fọ̀ ni yóò dípò aṣọ ẹ̀yẹ ìjóná dípò ẹwà.

25. Àwọn ọkùnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú,àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lójú ogun.

26. Àwọn bodè Síònì yóò sunkún kíkorò, wọn ó ṣọ̀fọ̀,nítorí ó dahoro, yóò jókòó ní orí ilẹ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 3