Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 25:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòsìààbò fún aláìní nínú ìpọ́njúu rẹ̀ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjìbòòji kúrò lọ́wọ́ ooru.Nítorí pé èémí àwọn ìkàdàbí ìjì tí ó bì lu ògiri

5. àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní ihà.O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì,gẹ́gẹ́ bí òjìji kùrukùru ṣe ń dín ooru kù,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́.

6. Ní ori òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogunyóò ti pèṣèàṣè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyànàpèjẹ ti wáìnì àtijọ́ti ẹran tí ó dára jù àti ti wáìnìtí ó gbámúṣé.

7. Ní orí òkè yìí ni yóò parunaṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn,abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀ èdè mọ́lẹ̀;

8. Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé. Olúwa gbogbo ayé yóò sì nu gbogbo omijé nù,kúrò ní ojúu gbogbo wọn;Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn an rẹ̀ kúròní gbogbo ilẹ̀ ayé. Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

Ka pipe ipin Àìsáyà 25