Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 22:6-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Élámù mú àpò-ọfà lọ́wọ́,pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin,kírí yọ apata rẹ̀ síta.

7. Àyànfẹ́ àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́-ogun,àwọn ẹlẹ́ṣin ni a sọdó sí ẹnu bodè ìlú;

8. gbogbo ààbò Júdà ni a ti ká kúrò.Ìwọ sì gbójú sókè ní ọjọ́ náàsí àwọn ohun ìjà ní ààfin ti inú ihà,

9. Ìwọ rí i pé ìlúu Dáfídìní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè níbi ààbò rẹ̀,ìwọ ti tọ́jú omisínú adágún ti ìsàlẹ̀.

10. Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jérúsálẹ́mùó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ìgànná lágbára.

11. Ìwọ mọ agbemi sí àárin ògiri méjìfún omi inú adágún àtijọ́,ṣùgbọ́n ìwọ kò wo ẹni tí ó ṣe é tẹ́lẹ̀tàbí kí o kọbi ara sí ẹni tí ógbérò rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ ṣẹ́yìn.

12. Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun,pè ọ́ ní ọjọ́ náàláti ṣunkún kí o sì pohùnréré,kí o tu irun rẹ dànù kí o sìda aṣọ ọ̀fọ̀ bora.

13. Ṣùgbọ́n Wòó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wàmàlúù pípa àti àgùntàn pípa,ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu!“Jẹ́ kí a jẹ kí a mu,” ni ẹ̀yin wí,“Nítorí pé lọ́la àwa ó kú!”

14. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mímọ̀ létíì mi: “Títí di ọjọ́ ikúu yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

15. Èyí ni ohun tí Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé,fún Ṣébínà, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ọ rẹ̀:

16. Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín-yìí àti péta ni ó sì fún ọ ní àṣẹláti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín-yìí,tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gígatí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta?

17. “Kíyèṣára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígíríkí ó sì jù ọ́ nù, Ìwọ ọkùnrin alágbára.

Ka pipe ipin Àìsáyà 22