Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 22:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ àfonífojì ti ìran:Kí ni ó ń dààmú un yín báyìí,tí gbogbo yín fi gun orí òrùlé lọ,

2. Ìwọ ìlú tí ó kún fún dàrúdàpọ̀,Ìwọ ìlú rúkèrúdò òun rògbòdìyànÀwọn tó ṣubú nínú un yín ni a kò fi idà pa,tàbí ojú ogun ni wọ́n kú sí.

3. Gbogbo àwọn olóríi yín ti jùmọ̀ sálọ;a ti kó wọn nígbékùn láì lo ọrun ọfà.Ẹ̀yin tí a mú ni a ti kó lẹ́rú papọ̀,lẹ́yìn tí ẹ ti sá nígbà tí ọ̀ta sì wàlọ́nà jínjìnréré.

4. Nítorí náà ni mo wí pé, “Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi:jẹ́ kí n ṣunkún kíkorò.Má ṣe gbìyànjú àti tùmí nínúnítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.”

5. Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kantí rúkèrúdò, rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ní àfonífojì ìmọ̀,ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀àti síṣun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè.

6. Élámù mú àpò-ọfà lọ́wọ́,pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin,kírí yọ apata rẹ̀ síta.

7. Àyànfẹ́ àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́-ogun,àwọn ẹlẹ́ṣin ni a sọdó sí ẹnu bodè ìlú;

8. gbogbo ààbò Júdà ni a ti ká kúrò.Ìwọ sì gbójú sókè ní ọjọ́ náàsí àwọn ohun ìjà ní ààfin ti inú ihà,

9. Ìwọ rí i pé ìlúu Dáfídìní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè níbi ààbò rẹ̀,ìwọ ti tọ́jú omisínú adágún ti ìsàlẹ̀.

10. Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jérúsálẹ́mùó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ìgànná lágbára.

11. Ìwọ mọ agbemi sí àárin ògiri méjìfún omi inú adágún àtijọ́,ṣùgbọ́n ìwọ kò wo ẹni tí ó ṣe é tẹ́lẹ̀tàbí kí o kọbi ara sí ẹni tí ógbérò rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ ṣẹ́yìn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 22