Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 20:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Lẹ́yìn náà ni Olúwa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí Ìránṣẹ́ mi Àìsáyà ti lọ káàkiri ní ìhòòhò àti láì wọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí àmì àti àpẹẹrẹ sí Éjíbítì àti Kúṣì,

4. bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Áṣíríà yóò kó àwọn ìgbèkùn Éjíbítì lọ ní ìhòòhò àti láì wọ bàtà pẹ̀lú àwọn àtìpó Kúṣì, ọ̀dọ́ àti àgbà, pẹ̀lú ìbàdí goloto—bí àbùkù Éjíbítì.

5. Gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Kúṣì tí wọ́n sì ń fi Éjíbítì yangàn ni ẹ̀rù yóò dé bá tí a ó sì dójútì wọ́n.

6. Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ní etí òkun yóò wí pé, ‘Wo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a ti gbọ́kànlé, àwọn tí a sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ láti ọwọ́ ọba Ásíríà! Báwo ni a ó ṣe sálà?’ ”

Ka pipe ipin Àìsáyà 20