Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 16:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Móábù gbé pẹ̀lúù rẹ,jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.”Aninilára yóò wá sí òpin,ìparun yóò dáwọ́;òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀.

5. Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀,ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lóríi rẹ̀—ọ̀kan láti ilé Dáfídì wá.Ẹni nní ti ìdájọ́ ń wá ẹ̀tọ́tí ó sì fi ìyára wá ohun tí í ṣe òdodo.

6. Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Móábù—Wábiwọ́sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge,gààrùu rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀—ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.

7. Nítorí náà ni àwọn ará Móábù pohùnréréwọ́n jùmọ̀ pohùnréré lórí Móábù.Ṣunkún kí o sì banújẹ́fún àwọn ọkùnrin ìlú Hárésétì.

Ka pipe ipin Àìsáyà 16