Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 15:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Hẹ́ṣíbónì àti Élíálè ké ṣóde,ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jáhásì.Nítorí náà ni àwọn ọmọ ogun Móábù ṣe kígbetí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ́sì.

5. Ọkàn mi kígbe lórí Móábù;àwọn ìṣáǹṣá rẹ sálà títí dé Ṣóárì,títí fi dé Égílátì Ṣẹ́líṣíyà.Wọ́n gòkè lọ títí dé Lúhítìwọ́n ń ṣunkún bí wọ́n ti ń lọ,Ní òpópónà tí ó lọ sí Hórónáímùwọ́n ń pohùnréré ìparun wọn

6. Gbogbo omi Nímírímù ni ó ti gbẹàwọn koríko sì ti gbẹ,gbogbo ewéko ti tánewé tútù kankan kò sí mọ́.

Ka pipe ipin Àìsáyà 15