Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 15:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Móábù:A pa Árì run ní Móábù,òru kan kí a paárun!A pa Kárì run ní Móábù,òru kan kí a paárun!

2. Díbónì gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlìi rẹ̀,sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti ṣunkún,Móábù pohùnréré lórí Nébónì àti Médíbà.Gbogbo orí ni a fágbogbo irungbọ̀n ni a gé dànù.

3. Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà,ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede àkójọwọ́n pohùnréré,Wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.

4. Hẹ́ṣíbónì àti Élíálè ké ṣóde,ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jáhásì.Nítorí náà ni àwọn ọmọ ogun Móábù ṣe kígbetí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ́sì.

Ka pipe ipin Àìsáyà 15