Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 14:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa yóò fi àánú hàn fún Jákọ́bù,yóò tún Ísírẹ́lì yàn lẹ́ẹ̀kan síiyóò sì fi ìdíi wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn.Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn,wọn yóò sì fọwọ́ṣowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilée Jákọ́bù.

2. Àwọn orílẹ̀ èdè yóò gbà wọ́nwọn yóò sì mú wọn wá sí àyèe wọn.Ilé Ísírẹ́lì yóò gba àwọn orílẹ̀ èdègẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrinní ilẹ̀ Olúwa.Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùnwọn yóò sì jọba lórí àwọn amúnisìn wọn.

3. Ní ọjọ́ tí Olúwa yóò fi ìtùra fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà,

4. ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Bábílónì pé:Báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin!Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí!

5. Olúwa ti dá ọ̀pá ìkà náà,ọ̀pá àwọn aláṣẹ,

6. èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró,nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀ èdèpẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin.

7. Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà,wọ́n bú sí orin.

8. Pẹ̀lú pẹ̀lù àwọn igi Páínì àti àwọnigi kédárì ti Lẹ́bánónìń yọ̀ lóríì rẹ ó wí pé,“Níwọ̀n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí,kò sí alagi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.”

9. Ibojì tí ó wà ní ìṣàlẹ̀ ni a ru sókèláti pàdé rẹ ní àpadàbọ̀ rẹ̀ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ ṣókè láti wá kí ọgbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayéó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ẹ wọngbogbo àwọn tí ó jọba lórí àwọn orílẹ̀ èdè.

10. Gbogbo wọn yóò dáhùn,wọn yóò wí fún ọ wí pé,“Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lúìwọ náà ti dàbí wa.”

11. Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì,pẹ̀lú ariwo àwọn hápù rẹ,àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹàwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀.

12. Báwo ni ìwọ ṣe ṣubúlulẹ̀ láti ọ̀run wá,ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà!A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayéÌwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀ èdè ba rí!

13. Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé,“Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run;Èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókèga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run,Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpèjọní ṣónṣó orí òkè mímọ́.

14. Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọ̀sánmọ̀;Èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá ògo.”

15. Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọlọ sí ìṣàlẹ̀ ọ̀gbun.

16. Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ,wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ:“Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtìtí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.

Ka pipe ipin Àìsáyà 14