Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 12:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,Èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù. Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,òun ti di ìgbàlà mi.”

3. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omiláti inú un kànga ìgbàlà.

4. Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé:“Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,Jẹ́ kí ó di mímọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè,ohun tí ó ti ṣekí o sì kéde pé a ti gbéorúkọ rẹ̀ ga.

5. Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo,jẹ́ kí èyí di mímọ̀ fún gbogbo ayé.

6. Kígbe ṣókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ṣíhónì,nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kanṣoṣoti Ísírẹ́lì láàrin yín.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 12