Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 11:4-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní,pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnufún àwọn aláìní ayé.Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀,pẹ̀lú ooru ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.

5. Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ ká.

6. Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé,àmọ̀tẹ́kùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìúnàti ọmọ ẹran ó wà papọ̀ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n.

7. Màlúù àti béárì yóò máa jẹun pọ̀,àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀,kìnnìún yóò sì máa jẹ koríkogẹ́gẹ́ bí akọ màlúù.

8. Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká,Ọmọdé yóò ki ọwọ́ọ rẹ̀ bọ ìtẹ́ẹ paramọ́lẹ̀.

9. Wọn kò ní ṣeni lọ́ṣẹ́ tàbí panirunní gbogbo òkè mímọ́ mi,nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwagẹ́gẹ́ bí omi ti í bo òkun.

10. Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jéésè yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àṣíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀ èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo.

11. Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Ásíríà wá, láti ìsàlẹ̀ Éjíbítì àti Òke Éjíbítì, láti Kúṣì, láti Élámù láti Babilóníà, láti Hámátì àti láti àwọn erékùṣù inú òkun.

12. Òun yóò gbé àṣíá sókè fún àwọn orílẹ̀ èdè,yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Ísírẹ́lì jọ,yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Júdà tí a ti fọ́n káàkiri jọ,láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.

Ka pipe ipin Àìsáyà 11