Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 11:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Owú jíjẹ Éfáímù yóò pòórá,àwọn ọ̀tá Júdà ni a ó ké kúrò,Éfáímù kò ní jowúu Júdà,tàbí Júdà kó dojú kọ Éfáímù.

14. Wọn yóò dìgbòlu àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́Fílísítíà ni apá ìwọ̀ oòrùn,wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọnènìyàn apá ìlà oòrùn.Wọn yóò gbé ọwọ́ọ wọn lé Édómù àti Móábù,àwọn ará Ámónì yóò sì di ìwẹ̀fàa wọn.

15. Olúwa yóò sọ di gbígbéàyasí òkun Éjíbítì,pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ọ rẹ̀,kọjá lórí odò Éúfírétì.Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méjetó fi jẹ́ pé àwọn ènìyànyóò máa là á kọjá pẹ̀lúu bàtà.

Ka pipe ipin Àìsáyà 11