Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 1:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. “Ọpọ̀lọpọ̀ ẹbọ yínkín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni Olúwa wí.“Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísunti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa,Èmi kò ní inú dídùnnínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntànàti ti orúkọ.

12. Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi,ta ni ó bèèrè èyí lọ́wọ́ ọ yín,Gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi?

13. Ẹ má mú ọrẹ aṣán wá mọ́!Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi,oṣù tuntun, ọjọ́ ọ̀sẹ̀ àti àwọn àpèjọÈmi kò lè faradà àpèjọ ibi yín wọ̀nyí.

14. Ayẹyẹ oṣù tuntun yín àti àpèjẹtí ẹ yà ṣọ́tọ̀ni ọkàn mi kórìíra.Wọ́n ti di àjàgà sí mi ní ọrùn,Ó ti sú mi láti máa fara dà wọ́n.

15. Nigbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sóke ni àdúrà,Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín,kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà,Èmi kò ni tẹ́ti sí i.Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.

16. Wẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ara yín mọ́.Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi!Dáwọ́ àìṣedéédéé dúró,

Ka pipe ipin Àìsáyà 1