Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 8:6-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Dáfídì sì fi àwọn ológún sí Síríà ti Dámásíkù: àwọn ará Síríà sì wá sin Dáfídì, wọn a sì máa mú ẹ̀bùn wá, Olúwa sì pa Dáfídì mọ́ níbikíbi tí o ń lọ.

7. Dáfídì sì gba àṣà wúrà tí ó wà lára àwọn ìránṣẹ Hadadésérì, ó sì kó wọn wá sí Jérúsálẹ́mù.

8. Láti Bétà, àti láti Bérótáì, àwọn ìlú Hadadésérì, ni Dáfídì ọba sì kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ baba wá.

9. Nígbà tí Tóù ọba Hámátì sì gbọ́ pé Dáfídì ti pa gbogbo ogun Hadadésérì.

10. Tóì sì rán Jórámù ọmọ rẹ̀ sí Dáfídì ọba, láti kí i, àti láti súre fún un, nítorí pé ó tí bá Hadadésérì jagun, ó sì ti pa á: nítorí tí Hadadésérì sáà ti bá Tóù jagun. Jórámù sì ni ohun èlò fàdákà, àti ohun èlò wúrà, àti ohun èlò idẹ ní ọwọ́ rẹ̀.

11. Dáfídì ọba sì fi wọ́n fún Olúwa pẹ̀lú fàdákà, àti wúrà tí ó yà sí mímọ́, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ àwọn orilẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹ́gun.

12. Lọ́wọ́ Síría àti lọ́wọ́ Móábù àti lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ámónì, àti lọ́wọ́ àwọn Fílístínì, àti lọ́wọ́ Ámálékì, àti nínú ìkógun Hadadésérì ọmọ Réhóbù ọba Sóbà.

13. Dáfídì sì ní òkìkí gidigidi nígbà tí ó padà wá ilé láti ibi pípa àwọn ará Síríà ní àfonífojì iyọ̀, àwọn tí o pa jẹ́ ẹgbaàsán ènìyàn.

14. Ó sì fi àwọn ológun sí Édómù; àti ní gbogbo Édómù yíká ni òun sì fi ológun sí, gbogbo àwọn tí ó wà ní Édómù sì wá sin Dáfídì, Olúwa sì fún Dáfídì ní ìṣẹgún níbikíbi tí ó ń lọ.

15. Dáfídì sì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì; Dáfídì sì ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́ fún àwọn ènìyàn rẹ̀.

16. Jóábù ọmọ Sérúyà ni ó sì ń ṣe olórí ogun; Jéhóṣáfátì ọmọ Áhílúdì sì ń ṣe akọ̀wé.

17. Sádókù ọmọ Áhítúbì, àti Áhímélékì ọmọ Ábíátarì, ni àwọn àlùfáà; Sérúyà a sì máa ṣe akọ̀wé.

18. Bénáyà ọmọ Jéhóíádà ni ó sì ń ṣe olórí àwọn Kérétì, àti àwọn Pélétì; àwọn ọmọ Dáfídì sì jẹ́ aláṣẹ.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 8