Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 5:7-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ṣùgbọ́n Dáfídì fi agbára gba ìlú odì Síónì: èyí náà ni í ṣe ìlú Dáfídì.

8. Dáfídì sọ lọ́jọ́ náà pé, “Ẹnikẹ́ni tí yóò kọlu àwọn ará Jébúsì, jẹ́ kí ó gba ojú àgbàrá, kí o sí kọlu àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú tí ọkàn Dáfídì kórìíra.” Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí pé, “Afọ́jú àti arọ wà níbẹ̀, kì yóò lè wọlé.”

9. Dáfídì sì jókòó ní ilé àwọn ọmọ ogun tí ó ní odi, a sì ń pè é ní ìlú Dáfídì. Dáfídì mọ ìgànná yí i ká láti Mílò wá, ó sì kọ́ ilé nínú rẹ̀.

10. Dáfídì sì ń pọ̀ si i, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì wà pẹ̀lú rẹ̀.

11. Hírámù ọba Tírè sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dáfídì, àti igi kédárì, àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn tí ń gbẹ́ òkúta, wọ́n kọ́ ilé kan fún Dáfídì.

12. Dáfídì sì kíyèsi i pé, Olúwa ti fi ìdí òun múlẹ̀ láti jọba lórí Ísírẹ́lì, àti pé, ó gbé ìjọba rẹ̀ ga nítorí Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀.

13. Dáfídì sì tún mú àwọn àlè àti aya sí i láti Jérúsálẹ́mù wá, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti Hébírónì bọ̀: wọ́n sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin fún Dáfídì.

14. Èyí sì ni orúkọ àwọn tí a bí fún un ní Jérúsálẹ́mù; Ṣamímúà àti Sóbábù, àti Nátanì, àti Sólómónì.

15. Àti Íbéhárì, àti Élíṣúà, àti Néfégì, àti Jáfíà.

16. Àti Élíṣámà, àti Élíádà, àti Élífélétì.

17. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Fílístínì gbọ́ pé, wọ́n ti fi Dáfídì jọba lórí Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn Fílístínì sì gòkè wá láti wá Dáfídì; Dáfídì sì gbọ́, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú olódì.

18. Àwọn Fílístínì sì wá, wọ́n sì tẹ ara wọn ní àfonífojì Réfáímù.

19. Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Kí èmi ó gòkè tọ àwọn Fílístínì bí? Ìwọ ó fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ bí?” Olúwa sì wí fún Dáfídì pé, “Gòkè lọ, nítorí pé dájúdájú èmi ó fi àwọn Fílístínì lé ọ lọ́wọ́.”

20. Dáfídì sì dé Baal-Perasímù, Dáfídì sì pa wọ́n níbẹ̀, ó sì wí pé, “Olúwa ti ya lu àwọn ọta mi níwájú mi, gẹ́gẹ́ bí omi ti ń ya.” Nítorí náà ni òun ṣe pe orúkọ ibẹ̀ náà ni Baal-Perasímù.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 5