Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 24:17-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Dáfídì sì wí fún Olúwa nígbà tí ó rí ańgẹ́li tí ń kọlu àwọn ènìyàn pé, “Wò ó, èmi ti ṣẹ̀, èmi sì ti hùwà búburú ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn wọ̀nyí, kín ni wọ́n ha ṣe? Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, kí ó wà lára mi àti ìdílé baba mi.”

18. Gádì sì tọ Dáfídì wá lọ́jọ́ náà, ó sì wí fún un pé, “Gòkè, tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa níbi ìpakà Áráúnà ará Jébúsì.”

19. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Gádì, Dáfídì sì gòkè lọ bí Olúwa ti pa á láṣẹ.

20. Áráúnà sì wò, ó sì rí ọba àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ wá lọ́dọ̀ rẹ̀: Áráúnà sì jáde, ó sì wólẹ̀ níwájú ọba ó sì dojú rẹ̀ bolẹ̀.

21. Áráúnà sì wí pé, “Nítorí kín ni Olúwa mi ọba ṣe tọ ìránṣẹ́ rẹ̀ wá?”Dáfídì sì dáhùn pé, “Láti ra ibi ìpakà rẹ lọ́wọ́ rẹ, láti tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa, kí àrùn ìparun lè dá lára àwọn ènìyàn náà.”

22. Áráúnà sì wí fún Dáfídì pé, “Jẹ́ kí Olúwa mi ọba ó mú èyí tí ó dára lójú rẹ̀, kí o sì fi í rúbọ: wò ó, màlúù nìyìí láti fi ṣe ẹbọ sísun, àti ohun èlò ìpakà, àti ohun èlò mìíràn ti màlúù fún igi.

23. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni Áráúnà fi fún ọba, bí ọba. Áráúnà sì wí fún ọba pé, Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ ó gba ọrẹ rẹ.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 24