Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 21:7-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ṣùgbọ́n Ọba dá Méfíbóṣétì sí, ọmọ Jónátanì, ọmọ Ṣọ́ọ̀lù, nítorí ìbúra Olúwa tí ó wà láàrin Dáfídì àti Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù.

8. Ọba sì mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rísípà ọmọbìnrin Áíyà bí fún Ṣọ́ọ̀lù, àní Ámónì àti Méfíbóṣétì àwọn ọmọkùnrin máràrùn ti Mérábù, ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù, àwọn tí ó bí fún Ádíríélì ọmọ Básílíà ará Méhólátì.

9. Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Gíbéà lọ́wọ́, wọ́n sì so wọ́n rọ̀ lórí òkè níwájú Olúwa: àwọn méjèèjì sì ṣubú lẹ́ẹ̀kan, a sì pa wọ́n ní ìgbà ìkórè, ní ìbẹ̀rẹ̀, ìkórè ọkà-báálì.

10. Rísípà ọmọbìnrin Áíyà sì mú aṣọ ọ̀fọ̀ kan, ó sì tẹ́ fún ará rẹ̀ lórí àpáta ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí omi fi dà sí wọn lára láti ọ̀run wá, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn lọ́sán-an, tàbí àwọn ẹranko ìgbẹ́ lóru.

11. A sì ro èyí, tí Rísípà ọmọbìnrin Áíyà obìnrin Ṣọ́ọ̀lù ṣe, fún Dáfídì.

12. Dáfídì sì lọ ó sì kó egungun Ṣọ́ọ̀lù, àti egungun Jónátánì ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin Jábéṣì-Gíléádì, àwọn tí ó jí wọn kúrò ní ìta Bẹti-Sánì, níbi tí àwọn Fílístínì gbé so wọ́n rọ̀, nígbà tí àwọn Fílístínì pa Sọ́ọ̀lù ní Gílíbóà.

13. Ó sì mú egungun Sọ́ọ̀lù àti egungun Jónátánì ọmọ rẹ̀ láti ibẹ̀ náà wá; wọ́n sì kó egungun àwọn tí a ti so rọ̀ jọ.

14. Wọ́n sì sin egungun Sọ́ọ̀lù àti ti Jònátánì ọmọ rẹ̀ ní ilé Bẹ́ńjámínì, ní Sélà, nínú ibojì Kíṣì baba rẹ̀: wọ́n sì ṣe gbogbo èyí tí ọba paláṣẹ: lẹ́yìn èyí ni Ọlọ́run si gba ẹ̀bẹ̀ nítorí ilẹ̀ náà.

15. Ogun sì tún wà láàrin àwọn Fílístínì àti Ísírẹ́lì; Dáfídì sì sọ̀kalẹ̀, àti àwọn ìránṣẹ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì bá àwọn Fílístínì jà: ó sì rẹ Dáfídì.

16. Iṣibi-bénóbù sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òmìrán, ẹni tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ wọn ọ̀dúnrún ṣékélì idẹ, ó sì sán idà tuntun, ó sì gbèrò láti pa Dáfídì.

17. Ṣùgbọ́n Ábíṣáì ọmọ Sérúíà ràn án lọ́wọ́, ó sì kọlu Fílístínì náà, ó sì paá, Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì búra fún un pé, “Ìwọ kì yóò sì tún bá wa jáde lọ sí ibi ìjà mọ́ kí iwọ má ṣe pa iná Ísírẹ́lì.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 21