Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 21:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìyàn kan sì mú lọ́jọ́ Dáfídì ní ọdún mẹ́ta, láti ọdún dé ọdún; Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa sì wí pé, Nítorí ti Ṣọ́ọ̀lù ni, àti nítorí ilé rẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀jẹ̀, nítorí pé ó pa àwọn ará Gíbíónì.

2. Ọba sì pe àwọn ará Gíbíónì, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; àwọn ará Gíbíónì kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ àwọn tí ó kù nínú àwọn ọmọ Ámórì; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti búra fún wọn: Ṣọ́ọ̀lù sì ń wá ọ̀nà àti pa wọ́n ní ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà.

3. Dáfídì sì bi àwọn ará Gíbíónì léèrè pé, “Kí ni èmi ó ṣe fún un yín? Àti kìn ni èmi ó fi ṣe ètùtù, kí ẹ̀yin lè súre fún ilẹ̀ ìní Olúwa?”

4. Àwọn ará Gíbíónì sì wí fún un pé, “Kì í ṣe ọ̀rọ̀ fàdákà tàbí wúrà láàrin wa àti Ṣọ́ọ̀lù tàbí ìdílé rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fẹ́ kí ẹ pa ẹnìkan ní Ísírẹ́lì.”Dáfídì sì wí pé, “Èyí tí ẹ̀yin bá wí ni èmi ó ṣe?”

5. Wọ́n sì wí fún ọba pé, “Ọkùnrin tí ó run wá, tí ó sì rò láti pa wá rẹ́ ki a má kù níbikíbi nínú gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì.

6. Mú ọkùnrin méje nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún wá, àwa ó sì so wọ́n rọ̀ fún Olúwa ní Gíbéà ti Ṣọ́ọ̀lù ẹni tí Olúwa ti yàn.”Ọba sì wí pé, “Èmi ó fi wọ́n fún yín.”

7. Ṣùgbọ́n Ọba dá Méfíbóṣétì sí, ọmọ Jónátanì, ọmọ Ṣọ́ọ̀lù, nítorí ìbúra Olúwa tí ó wà láàrin Dáfídì àti Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù.

8. Ọba sì mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rísípà ọmọbìnrin Áíyà bí fún Ṣọ́ọ̀lù, àní Ámónì àti Méfíbóṣétì àwọn ọmọkùnrin máràrùn ti Mérábù, ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù, àwọn tí ó bí fún Ádíríélì ọmọ Básílíà ará Méhólátì.

9. Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Gíbéà lọ́wọ́, wọ́n sì so wọ́n rọ̀ lórí òkè níwájú Olúwa: àwọn méjèèjì sì ṣubú lẹ́ẹ̀kan, a sì pa wọ́n ní ìgbà ìkórè, ní ìbẹ̀rẹ̀, ìkórè ọkà-báálì.

10. Rísípà ọmọbìnrin Áíyà sì mú aṣọ ọ̀fọ̀ kan, ó sì tẹ́ fún ará rẹ̀ lórí àpáta ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí omi fi dà sí wọn lára láti ọ̀run wá, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn lọ́sán-an, tàbí àwọn ẹranko ìgbẹ́ lóru.

11. A sì ro èyí, tí Rísípà ọmọbìnrin Áíyà obìnrin Ṣọ́ọ̀lù ṣe, fún Dáfídì.

12. Dáfídì sì lọ ó sì kó egungun Ṣọ́ọ̀lù, àti egungun Jónátánì ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin Jábéṣì-Gíléádì, àwọn tí ó jí wọn kúrò ní ìta Bẹti-Sánì, níbi tí àwọn Fílístínì gbé so wọ́n rọ̀, nígbà tí àwọn Fílístínì pa Sọ́ọ̀lù ní Gílíbóà.

13. Ó sì mú egungun Sọ́ọ̀lù àti egungun Jónátánì ọmọ rẹ̀ láti ibẹ̀ náà wá; wọ́n sì kó egungun àwọn tí a ti so rọ̀ jọ.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 21