Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 20:15-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Wọ́n wá, wọ́n sì dó tì í ní Ábélì tí Bẹti Máákà, wọ́n sì mọ odí ti ìlú náà, odi náà sì dúró ti odi ìlú náà, gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ Jóábù sì ń gbìyànjú láti wó ògiri náà lulẹ̀.

16. Obìnrin ọlọ́gbọ́n kan sì kígbe sókè láti ìlú náà wá pé, “Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀! Èmi bẹ̀ yín, ẹsọ fún Jóábù pé: Súnmọ́ ìhìnyìí èmi ó sì bá a sọ̀rọ̀.”

17. Nígbà tí òun sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, obìnrin náà sì wí pé, “Ìwọ ni Jóábù bí?”Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi náà ni.”Obìnrin náà sì wí fún un pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́-bìnrin rẹ.”Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi ń gbọ́.”

18. Ó sì sọ̀rọ̀ wí pé, “Wọ́n ti ń wí ṣáájú pé, ‘Níti bíbéèrè, wọn ó béèrè ní Ábélì’ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì parí ọ̀ràn náà.

19. Èmi ni ọ̀kan nínú àwọn ẹni àlàáfíà àti tòótọ́ ní Ísírẹ́lì: ìwọ ń wá ọ̀nà láti pa ìlú kan run tí ó jẹ́ ìyá ní Ísírẹ́lì: èéṣe tí ìwọ ó fi gbé ìní Olúwa mì.”

20. Jóábù sì dáhùn wí pé, “Kí a má rí i, kí a má rí i lọ́dọ̀ mi pé èmi gbé mì tàbí èmi sì parun.

21. Ọ̀ràn náà kò sì rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ọkùnrin kan láti òkè Éfúráímù, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣébà, ọmọ Bíkírì, ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sòkè sí ọba, àní sí Dáfídì: fi òun nìkanṣoṣo lé wa lọ́wọ́, èmi ó sì fi ìlú sílẹ̀.”Obìnrin náà sì wí fún Jóábù pé, “Wò ó, orí rẹ̀ ni a ó sì sọ láti inú odì wá.”

22. Obìnrin náà sì mú ìmọ́ran rẹ̀ tọ gbogbo àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì bẹ Ṣébà ọmọ Bíkírì lórí, wọ́n sì sọ ọ́ sí Jóábù. Òun sì fún ìpè, wọ́n sì túká sọ́dọ̀ ọba.

23. Jóábù sì ni olórí gbogbo ogun Ísírẹ́lì: Bénáyà ọmọ Jéhóiádà sì jẹ́ olórí àwọn Kérétì, àti ti àwọn Pélétì.

24. Ádórámù sì jẹ́ olórí àwọn agbowó òde: Jéhóṣáfátì ọmọ Áhílúdì sì jẹ́ olùkọsílẹ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ìlú.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 20