Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 17:2-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Èmi ó sì yọ sí i nígbà tí àárẹ̀ bá mú un tí ọwọ́ rẹ̀ sì ṣe aláìle, èmi ó sì dá a ní ìjì: gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ yóò sì sá, èmi ó sì kọlu ọba níkan ṣoṣo.

3. Èmi ó sì mú gbogbo àwọn ènìyàn padà sọ́dọ̀ rẹ bi ìgbà tí ìyàwó bá padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀. Ọkàn ẹnìkan ṣoṣo tí ìwọ ń wá yìí ni ó túmọ̀ sí ìpadàbọ̀ gbogbo wọn; gbogbo àwọn ènìyàn yóò sì wà ní àlàáfíà.”

4. Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú Ábúsálómù, àti lójú gbogbo àwọn àgbà Ísírẹ́lì.

5. Ábúsálómù sì wí pé, “Ǹjẹ́ pe Húṣáì ará Áríkì, àwa ó sì gbọ́ èyí tí ó wà lẹ́nu rẹ̀ pẹ̀lú.”

6. Húṣáì sì dé ọ̀dọ̀ Ábúsálómù, Ábúsálómù sì wí fún un pé, “Báyìí ni Áhítófélì wí, kí àwa ṣe bí ọ̀rọ̀ rẹ bí? Bí ko bá sì tọ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ wí.”

7. Húṣáì sì wí fún Ábúsálómù pé, “Ìmọ̀ tí Áhítófélì gbà yìí, kò dára nísinsin yìí.”

8. Húṣáì sì wí pé, “Ìwọ mọ baba rẹ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé alágbára ni wọ́n, wọ́n sì wà ní Kíkorò ọkàn bí àmọ̀tẹ́kùn tí a gbà ní ọmọ ni pápá: baba rẹ sì jẹ́ jagunjagun ọkùnrin kì yóò bá àwọn ènìyàn náà gbé pọ̀ lóru.

9. Kíyèsí i, ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ nísinsin yìí ni ihò kan, tàbí ní ibòmíràn: yóò sì ṣe, nígbà tí díẹ̀ nínú wọn bá kọ́ ṣubú, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ yóò sì wí pé, ‘Ìparun sì ń bẹ́ nínú àwọn ènìyàn tí ń tọ Ábúsálómù lẹ́yìn.’

10. Ẹni tí ó sì ṣe alágbára, tí ọkàn rẹ̀ sì dàbí ọkàn kìnnìun, yóò sì rẹ̀ ẹ́: nítorí gbogbo Ísírẹ́lì ti mọ̀ pé alágbára ni baba rẹ, àti pé, àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ jẹ́ alágbára.

11. “Nítorí náà èmi dámọ̀ràn pé: Kí gbogbo Ísírẹ́lì wọ́jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ, láti Dánì títí dé Bééríṣébà, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn létí òkun fún ọ̀pọ̀lọpọ̀; àti pé, kí ìwọ tìkárarẹ ó lọ sí ogun náà.

12. Àwá ó sì yọ sí i níbikíbi tí àwa o gbé rí i, àwa ó sì yí i ká bí ìrì ti ń ṣẹ̀ sí ilẹ̀ àní, ọkàn kan kì yóò kù pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

13. Bí o bá sì bọ́ sí ìlú kan, gbogbo Ísírẹ́lì yóò mú okùn wá sí ìlú náà, àwa ó sì fà á lọ sí odo, títí a kì yóò fi rí òkúta kékeké kan níbẹ̀.”

14. Ábúsálómù àti gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì sì wí pé, “Ìmọ̀ Húṣáì ará Áríkì sàn ju ìmọ̀ Áhítófélì lọ! Nítorí Olúwa fẹ́ láti yí ìmọ̀ rere ti Áhítófélì po.” Nítorí kí Olúwa lè mú ibi wá sórí Ábúsálómù.

15. Húṣáì sì wí fún Sádókù àti fún Ábíátarì àwọn àlùfáà pé, “Bàyìí ni Áhítófélì ti bá Ábúsálómù àti àwọn àgbà Ísírẹ́lì dámọ̀ràn: báyìí lèmi sì báa dámọ̀ràn.

16. Nítorí náà yára ránṣẹ́ nísinsin yìí kí o sì sọ fún Dáfídì pé, ‘Má ṣe dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà lálẹ́ yìí, ṣùgbọ́n yára rékọjá kí a má báa gbé ọba mì, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.’ ”

17. Jónátanì àti Áhímásì sì dúró ní Énrógélì ọ̀dọ́mọdébìnrin kan sì lọ, ó sì sọ fún wọn, wọ́n sì lọ wọ́n sọ fún Dáfídì ọba nítorí pé kí a má báà rí wọn pé wọ́n wọ ìlú.

18. Ṣùgbọ́n ọdọmọdékùnrin kan rí wọn, ó sì wí fún Ábúsálómù: ṣùgbọ́n àwọn méjèèjì sì yára lọ kúrò, wọ́n sì wá sí ilé ọkùnrin kan ní Báhúrímù, ẹni tí ó ní kànga kan ní ọgbà rẹ̀, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ sí ibẹ̀.

19. Obìnrin rẹ̀ sì mú nǹkán ó fi bo kanga náà, ó sì sá àgbàdo sórí rẹ̀, a kò sì mọ̀.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 17