Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 15:14-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Dáfídì sì wí fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wá lọ́dọ̀ rẹ̀ ni Jérúsálẹ́mù pé, “Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a sá lọ, nítorí pé kò sí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ Ábúsálómù; ẹ yára, kí a lọ kúrò, kí òun má báà yára lé wa bá, kí ó má sì mú ibi bá wa, kí ó má sì fi ojú idà pa ìlú run.”

15. Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa wa ọba ń fẹ́, wò ó, àwa ìránṣẹ rẹ̀ ti murá.”

16. Ọba sì jáde, gbogbo ilé rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ọba sì fì mẹ́wàá nínú àwọn obìnrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa sọ́ ilé.

17. Ọba sì jáde, gbogbo ènìyàn sì tẹ̀lé e, wọ́n sì dúró ní ibìkan tí ó jìnnà.

18. Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì kọjá sí ìwájú rẹ̀, àti gbogbo àwọn Kérétì, àti gbogbo àwọn Pélétì, àti gbogbo àwọn ará Gítì, ẹgbẹ̀ta ọmọkùnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Gátì wá, sì kọjá níwájú ọba.

19. Ọba sì wí fún Ítaì, ará Gítì pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá wa lọ pẹ̀lú, padà, kí o sì ba ọba jókòó; nítorí pé aléjò ni ìwọ, ìwọ sì ti fi ìlú rẹ sílẹ̀.

20. Lánàá yìí ni ìwọ dé, èmi ó ha sì mú kí ìwọ máa bá wá lọ kákiri lónìí bí? Èmi ń lọ sí ibikíbi tí mo bá rí: padà, kí o sì mú àwọn arakùnrin rẹ padà, kí àánú àti òtítọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”

21. Ítaì sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Bí Olúwa tí ń bẹ láàyè, àti bí Olúwa mi ọba ti ń bẹ láàyè, nítòótọ́ níbikíbi tí Olúwa mi ọba bá gbé wà, ìbáà ṣe nínú ikú, tàbí nínú ìyè, níbẹ̀ pẹ̀lú ni ìránṣẹ́ rẹ yóò gbé wà.”

22. Dáfídì sì wí fún Ítaì pé, “Lọ kí o sì rékọjá!” Ítaì ará Gítì náà sì rékọjá, àti gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọ kékèké tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

23. Gbogbo ìlú náà sì fi ohùn rara sunkún, gbogbo ènìyàn sì rékọjá; ọba sì rékọjá odò Kídírónì, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì rékọjá, sí ìhà ọ̀nà ijù.

24. Sì wò ó, Sádókù pẹ̀lú àti gbogbo àwọn ọmọ Léfì tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ń ru àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run: wọ́n sì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run náà sọ̀kalẹ̀; Ábíátarì sí gòkè, títí gbogbo àwọn ènìyàn sì fi dẹ́kun àti máa kọjá láti ìlú wá.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 15