Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 14:20-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Láti mú irú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá ni Jóábù ìránṣẹ́ rẹ ṣe ṣe nǹkan yìí: Olúwa mi sì gbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n ańgẹ́lì Ọlọ́run, láti mọ gbogbo nǹkan tí ń bẹ̀ ní ayé.”

21. Ọba sì wí fún Jóábù pé, “Wò ó, èmi ó ṣe nǹkan yìí: nítorí náà lọ, kí o sì mú ọmọdékùnrin náà Ábúsálómù padà wá.”

22. Jóábù sì wólẹ̀ ó dojú rẹ̀ bolẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì súre fún ọba. Jóábù sì wí pé, “Lónìí ni ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé, èmi rí oore-ọ̀fẹ́ gbà lójú rẹ, Olúwa mi, ọba, nítorí pé ọba ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.”

23. Jóábù sì dìde, ó sì lọ sí Géṣúrì, ó sì mú Ábúsálómù wá sí Jérúsálẹ́mù.

24. Ọba sì wí pé, “Jẹ́ kí ó yípadà lọ sí ilé rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó rí ojú mi.” Ábúsálómù sì yípadà sí ilé rẹ̀, kò sì rí ojú ọba.

25. Kó sì sí arẹ́wà kan ní gbogbo Ísírẹ́lì tí à bá yìn bí Ábúsálómù: láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ kò sí àbùkù kan lára rẹ̀.

26. Nígbà tí ó bá sì rẹ́ irun orí rẹ̀ (nítorí pé lọ́dọ̀ọdún ni òun máa ń rẹ́ ẹ. Nígbà tí ó bá wúwo fún un, òun a sì máa rẹ́ ẹ) òun sì wọn irun orí rẹ̀, ó sì jásí igba ṣẹ́kẹ́lì nínú òṣùwọ̀n ọba.

27. A sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún Ábúsálómù àti ọmọbìnrin kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Támárì: òun sì jẹ́ obìnrin tí ó lẹ́wà lójú.

28. Ábúsálómù sì gbé ni ọdún méjì ní Jérúsálẹ́mù kò sì rí ojú ọba.

29. Ábúsálómù sì ránṣẹ́ sí Jóábù, láti rán an sí ọba: ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì ránṣẹ́ lẹ́ẹ̀kejì òun kò sì fẹ́ wá.

30. Ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, oko Jóábù gbé ti èmi, ó sì ní ọkà níbẹ̀; ẹ lọ kí ẹ sì tinábọ̀ ọ́.” Àwọn ìrànṣẹ́ Ábúsálómù sì tinábọ oko náà.

31. Jóábù sì dìde, ó sì tọ Ábúsálómù wá ní ilé, ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi tinábọ oko mi?”

32. Ábúsálómù sì dá Jóábù lóhùn pé, “Wò ó, èmi ránṣẹ́ sí ọ, wí pé, ‘Wá níhìn-ín yìí, èmi ó sì rán ọ lọ sọ́dọ̀ ọba, láti béèrè pé, “Kí ni èmi ti Géṣúrì wá si? Ìbá sàn fún mí bí ó ṣe pé èmi wà lọ́hùn-ún ṣíbẹ̀!” ’ Ǹjẹ́ nísinsin yìí jẹ́ kí èmi lọ síwájú ọba bí ó bá sì ṣe ẹ̀bi ń bẹ nínú mi, kí ó pa mí.”

33. Jóábù sì tọ ọba wá, ó sì rò fún un: ó sì ránṣẹ́ pe Ábúsálómù, òun sì wá sọ́dọ̀ ọba, ó tẹríba fún un, ó sì dojú rẹ̀ bolẹ̀ níwájú ọba, ọba sì fi ẹnu ko Ábúsálómù lẹ́nu.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 14