Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 14:11-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ó sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí ọba ó rántí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má ṣe ní ipá láti ṣe iparun, kí wọn o má bá a pa ọmọ mi!”Òun sì wí pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láàyè ọ̀kan nínú irun orí ọmọ rẹ ki yóò bọ sílẹ̀.”

12. Obìnrin náà sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ sọ̀rọ̀ kán fún Olúwa mi ọba”Òun si wí pé, “Má a wí.”

13. Obìnrin náà sì wí pé, “Nítorí kínni ìwọ sì ṣe ro irú nǹkan yìí sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run? Nítorí pé ní sísọ nǹkan yìí ọba ní ẹ̀bi, nítorí pé ọba kò mú ìsáǹsá rẹ̀ bọ̀ wá ilé.

14. Nítorí pé àwa ó sáà kú, a ó sì dàbí omi tí a tú sílẹ̀ tí a kò sì lè ṣàjọ mọ́; nítorí bí Ọlọ́run kò ti gbà ẹ̀mí rẹ̀, ó sì ti ṣe ọ̀nà kí a má báa lé ìsáǹsá rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ.

15. “Ǹjẹ́ nítorí náà ni èmi sì ṣe wá sọ nǹkan yìí fún Olúwa mi ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ti dẹ́rùbà mí; ìránṣẹ́bìnrin rẹ sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ èmi ó sọ fún ọba; ó lè rí bẹ́ẹ̀ pé ọba yóò ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún un.

16. Nítorí pé ọba ò gbọ́, láti gbà ìránṣẹ́bìnrin rẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọkùnrin náà tí ó ń fẹ́ gé èmi àti ọmọ mi pẹ̀lú kúrò nínú ilẹ̀ ìní Ọlọ́run.’

17. “Ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ọba Olúwa mi yóò sì jásí ìtùnú; nítorí bí ańgẹ́lì Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni Olúwa mi ọba láti mọ rere àti búburú: Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.’ ”

18. Ọba sì dàhùn, ó sì wí fún obìnrin náà pé, “Má ṣe fi nǹkan tí èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ pamọ́ fún mi, èmi bẹ̀ ọ́.”Obìnrin náà wí pé, “Jẹ́ kí Olúwa mi ọba má a wí?”

19. Ọba sì wí pé, “Ọwọ́ Jóábù kò ha wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo èyí?”Obìnrin náà sì dáhùn ó sì wí pé, “Bí ẹ̀mí rẹ ti ń bẹ láàyè, Olúwa mi ọba, kò sí ìyípadà sí ọwọ́ ọ̀tún, tàbí sí ọwọ́ òsì nínú gbogbo èyí tí Olúwa mi ọba ti wí: nítorí pé Jóábù ìránṣẹ́ rẹ, òun ni ó rán mi, òun ni ó sì fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ lẹ́nu.

20. Láti mú irú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá ni Jóábù ìránṣẹ́ rẹ ṣe ṣe nǹkan yìí: Olúwa mi sì gbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n ańgẹ́lì Ọlọ́run, láti mọ gbogbo nǹkan tí ń bẹ̀ ní ayé.”

21. Ọba sì wí fún Jóábù pé, “Wò ó, èmi ó ṣe nǹkan yìí: nítorí náà lọ, kí o sì mú ọmọdékùnrin náà Ábúsálómù padà wá.”

22. Jóábù sì wólẹ̀ ó dojú rẹ̀ bolẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì súre fún ọba. Jóábù sì wí pé, “Lónìí ni ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé, èmi rí oore-ọ̀fẹ́ gbà lójú rẹ, Olúwa mi, ọba, nítorí pé ọba ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.”

23. Jóábù sì dìde, ó sì lọ sí Géṣúrì, ó sì mú Ábúsálómù wá sí Jérúsálẹ́mù.

24. Ọba sì wí pé, “Jẹ́ kí ó yípadà lọ sí ilé rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó rí ojú mi.” Ábúsálómù sì yípadà sí ilé rẹ̀, kò sì rí ojú ọba.

25. Kó sì sí arẹ́wà kan ní gbogbo Ísírẹ́lì tí à bá yìn bí Ábúsálómù: láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ kò sí àbùkù kan lára rẹ̀.

26. Nígbà tí ó bá sì rẹ́ irun orí rẹ̀ (nítorí pé lọ́dọ̀ọdún ni òun máa ń rẹ́ ẹ. Nígbà tí ó bá wúwo fún un, òun a sì máa rẹ́ ẹ) òun sì wọn irun orí rẹ̀, ó sì jásí igba ṣẹ́kẹ́lì nínú òṣùwọ̀n ọba.

27. A sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún Ábúsálómù àti ọmọbìnrin kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Támárì: òun sì jẹ́ obìnrin tí ó lẹ́wà lójú.

28. Ábúsálómù sì gbé ni ọdún méjì ní Jérúsálẹ́mù kò sì rí ojú ọba.

29. Ábúsálómù sì ránṣẹ́ sí Jóábù, láti rán an sí ọba: ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì ránṣẹ́ lẹ́ẹ̀kejì òun kò sì fẹ́ wá.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 14