Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 12:6-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Òun yóò sì san àgùntàn náà padà ní mẹ́rinmẹ́rin, nítorí tí ó ṣe nǹkan yìí àti nítorí tí kò ní àánú.”

7. Nátanì sì wí fún Dáfídì pé, “Ìwọ ni ọkùnrin náà Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Èmi fi ọ́ jọba lórí Ísírẹ́lì, èmi sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Ṣọ́ọ̀lù.

8. Èmi sì fi ilé olúwa rẹ fún ọ, àti àwọn obìnrin olúwa rẹ sí àyà rẹ, èmi sì fi ìdílé Ísírẹ́lì àti ti Júdà fún ọ; tí àwọn wọ̀nyí bá sì kéré jù fún ọ èmi ìbá sì fún ọ sí i jù bẹ́ ẹ̀ lọ.

9. Èéṣe tí ìwọ fi kẹ́gan ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ìwọ fi ṣe nǹkan tí ó burú lójú rẹ̀, àní tí ìwọ fi fi idà pa Ùráyà ará Hítì, àti tí ìwọ fi mú obìnrin rẹ̀ láti fi ṣe obìnrin rẹ, o sì fi idà àwọn ọmọ Ámónì pa á.

10. Ǹjẹ́ nítorí náà idà kì yóò kúró ní ilé rẹ títí láé; nítorí pé ìwọ gàn mí, ìwọ sì mú aya Úráyà ará Hítì láti ṣe aya rẹ.’

11. “Bàyìí ni Olúwa wí, Kíyèsí i, ‘Èmi ó jẹ́ kí ibi kí ó dìde sí ọ láti inú ilé rẹ wá, èmi ó sì gba àwọn obìnrin rẹ lójú rẹ, èmi ó sì fi wọ́n fún aládúgbò rẹ, òun ó sì bá àwọn obìnrin rẹ sùn níwájú òòrun yìí.

12. Àti pé ìwọ ṣe é ní ìkọ̀kọ̀: Ṣùgbọ́n èmi ó ṣe nǹkan yìí níwájú gbogbo Ísírẹ́lì, àti níwájú òòrun.’ ”

13. Dáfídì sì wí fún Nátanì pé, “Èmi ṣẹ̀ sí Olúwa!”Nátanì sì wí fún Dáfídì pé, “Olúwa pẹ̀lú sì ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò; ìwọ kì yóò kú.

14. Ṣùgbọ́n nítorí nípa ìwà yìí, ìwọ fi àyè sílẹ̀ fún àwọn ọ̀ta Olúwa láti sọ ọ̀rọ̀ òdì, ọmọ náà tí a ó bí fún ọ, kíkú ní yóò kú.”

15. Nátanì sì lọ sí ilé rẹ̀ Olúwa sì fi àrùn kọlu ọmọ náà tí obìnrin Úráyà bí fún Dáfídì, ó sì ṣe àìsàn púpọ̀.

16. Dáfídì sì bẹ Ọlọ́run nítorí ọmọ náà, Dáfídì sì gbààwẹ̀, ó sì wọ inú ilé lọ, ó sì dúbúlẹ̀ lorí ilé ni orú náà.

17. Àwọn àgbà ilé rẹ̀ sì dìde tọ̀ ọ́ lọ, láti gbé e dìde lórí ilé: ó sì kọ̀, kò sì bá wọn jẹun.

18. Ní ijọ́ keje, ọmọ náà sì kú. Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì bẹ̀rù láti wí fún un pé, ọmọ náà kú: nítorí tí wọ́n wí pé, “Kíyèsí i, nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láàyè, àwa sọ̀rọ̀ fún un, òun kọ̀ si gbọ́ ohùn wa! Ǹjẹ́ yóò ti ṣe ara rẹ̀ ní ìṣẹ́ tó, bí àwa bá wí fún un pé, ọmọ náà kú.”

19. Nígbà tí Dáfídì sì rí pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, Dáfídì sì kìyésí i, pé ọmọ náà kú: Dáfídì sì béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ọmọ náà kú bí?”Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ó kú.”

20. Dáfídì sì dìde ní ilẹ̀, ó sì wẹ̀, ó fi òróró pa ara, ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì wọ inú ilé Olúwa lọ, ó sì wólẹ̀ sin: ó sì wá sí ilé rẹ̀ ó sì bèèrè, wọ́n sì gbé òunjẹ kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì jẹun.

21. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì bí léèrè pé, “Kí lèyí tí ìwọ ṣe yìí? Nítorí ọmọ náà nígbà tí ó ń bẹ láàyè ìwọ gbààwẹ̀, o sì sunkún; ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ náà kú, ó dìde ó sì jẹun.”

22. Ó sì wí pé, “Nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láàyè, èmi gbààwẹ̀, èmi sì sunkún: nítorí tí Èmi wí pé, ‘Ta ni ó mọ̀ bí Ọlọ́run ó ṣàánú mi, kí ọmọ náà le yè.’

23. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti kú, nítorí kín ni èmi ó ṣe máa gbààwẹ̀? Èmi ha tún lè mú-un padà bí? Èmi ni yóò tọ̀ ọ́ lọ, òun kì yóò sì tún tọ̀ mí wá.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 12