Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 11:11-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ùráyà sì wí fún Dáfídì pé, “Àpótí-ẹ̀rí, àti Ísírẹ́lì, àti Júdà jókòó nínú àgọ́; àti Jóábù olúwa mi, àti àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi wà ní ibùdó ní pápá: èmi ó ha lọ sí ilé mi, láti jẹ ati lati mu, àti láti bá obìnrin mi sùn? Bí ìwọ bá wà láàyè, àti bí ẹ̀mí rẹ́ si ti ń bẹ láàyè, èmi kì yóò ṣe nǹkan yìí.”

12. Dáfídì sì wí fún Ùráyà pé, “Ṣì dúró níhìn ín lónìí, lọ́la èmi ó sì jẹ́ kí ìwọ ó lọ.” Ùráyà sì dúró ní Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ náà, àti ijọ́ kejì.

13. Dáfídì sì pè é, ó sì jẹ, ó sì mú nítorí rẹ̀; ó sì mu kí ọtí pa á; òun sì jáde ní alẹ́ lọ sí ibùsùn rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀kalẹ́ lọ sí ilé rẹ̀.

14. Ó sì ṣe ní òwúrọ̀, Dáfídì sì kọ̀wé sí Jóábù, ó fi rán Ùráyà.

15. Ó sì kọ sínú ìwé pé, “Fi Ùráyà ṣíwájú ibi tí ogun gbé le, kí ẹ sì fà sẹ́yìn, kí wọn lè kọ lù ú, kí ó sì kú.”

16. Ó sì ṣe nígbà tí Jóábù ṣe àkíyèsí ìlú náà, ó sì yan Úráyà sí ibi kàn ní ibi tí òun mọ̀ pé àwọn alágbára ọkùnrin ń bẹ níbẹ̀.

17. Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì jáde wá, wọ́n sì bá Jóábù jà: díẹ̀ sì ṣubú nínú àwọn ènìyàn náà nínú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, Ùráyà ará Hítì sì kú pẹ̀lú.

18. Jóábù sì ránṣẹ́ ó sì ro gbogbo nǹkan ogun náà fún Dáfídì.

19. Ó sì pàṣẹ fún ìránṣẹ́ náà pé, “Nígbà tí iwọ bá sì parí àti máa ro gbogbo nǹkan ogun náà fún ọba.

20. Bí ó bá ṣe pé, ibinú ọba bá fàru, ti òun sì wí fún ọ pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fí súnmọ́ ìlú náà láti bá wọn jà, ẹ̀yin kò mọ̀ pé wọn ó tafà láti orí odì wá.

21. Ta ni ó pa Ábímélékì ọmọ Jerubu-Bésétì? Kì í ṣe obìnrin ni ó yí òkúta ọlọ lù ú láti orí odi wá, tí ó sì kú ní Tébésì? Èé ha ti rí tí ẹ̀yín fi súnmọ́ odi náà? Ìwọ yóò sì wí fún-un pé, Ùráyà ìránṣẹ́ rẹ ará Hítì kú pẹ̀lú.’ ”

22. Ìránṣẹ́ náà sì lọ, ó sì wá, ó sì jẹ́ gbogbo iṣẹ́ tí Jóábù rán an fún Dáfídì.

23. Ìránṣẹ́ náà sì wí fún Dáfídì pé, “Nítòótọ́ àwọn ọkùnrin náà lágbára jù wá lọ, wọ́n sì jáde tọ̀ wá wá ní pápá, àwa sì tẹ̀lé wọn títí wọ́n fi dé ẹ̀yìn odi.

24. Àwọn tafàtafà sì ta sí ìránṣẹ́ rẹ láti orí odi wá, díẹ̀ nínú àwọn ìránṣẹ́ ọba sì kú, ìránṣẹ́ rẹ̀ Ùráyà ará Hítì sì kú pẹ̀lú.”

25. Dáfídì sì wí fún ìránṣẹ́ náà pé, “Báyìí ni ìwọ yóò wí fún Jóábù pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí nǹkan yìí burú ní ojú rẹ, nítorí pé idà a máa jẹ́ lọ́tún lósì, mú ìjà rẹ le sí ìlú náà, kí o sì bì í ṣubú.’ Kí ìwọ sì mú un lọ́kàn le.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 11