Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 1:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ikú Ṣọ́ọ̀lù, Dáfídì ti ibi tí ó ti ṣẹ́gun àwọn ará Ámálékì bọ̀, ó sì dúró ní Síkílágì ní ọjọ́ méjì.

2. Ní ọjọ́ kẹta, ọkùnrin kan dé láti ibi ibùdó Ṣọ́ọ̀lù, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya; àti erùpẹ̀ ní orí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dáfídì, ó wólẹ̀ fún un láti bu ọlá fún un.

3. Dáfídì sì béèrè pé, “Ibo ni ìwọ ti wá?”“Èmi sá láti ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”

4. Dáfídì béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” “Sọ fún mi.”Ó wí pé, “Àwọn ọkùnrin náà sá láti ojú ogun. Ọ̀pọ̀ wọn ṣubú, wọ́n sì kú. Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Jónátanì sì kú pẹ̀lú.”

5. Nígbà náà, ní Dáfídì sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọkùnrin rẹ̀ Jónátanì ti kú.”

6. “Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sọ pé, mo wà ní orí òkè Gílíbóà níbẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù fi ara tí ọkọ̀ rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin sì ń lépa rẹ̀.

7. Nígbà tí ó wò yíká, tí ó rí mí, ó pè mi, mo sì wí pé, kí ni mo lè ṣe?

8. “Ó bi mí wí pé, ‘Ta ni ìwọ?’“Mo dáhùn pé, ‘Ará a Ámálékì,’

9. “Nígbà náà ó wí fún mi pé, ‘Dúró lórí ì mi kí o sì pa mí! Èmi wà nínú ìrora ikú, ṣùgbọ́n mo wà láàyè.’

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 1