Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 9:23-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Jórámù yípò padà, ó sì sá lọ ó sì ń pe Áhásáyà, “ó ṣe ìwà àrékérekè, Áhásáyà!”

24. Nígbà náà, Jéhù fa ọrun rẹ̀, ó sì yin Jórámù láàárin èjìká méjèèjì. Ọfà náà sì wọ inú ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú lulẹ̀ láti orí kẹ̀kẹ́ rẹ̀.

25. Jéhù sọ fún Bídíkárì, balógun kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ pé, “Gbé e sókè kí ó sì jù ú sí orí pápá tí ó jẹ́ ti Nábótì ará Jésérẹ́lì. Rantí bí èmi àti ìwọ ti ń gun kẹ̀kẹ́ papọ̀ lẹ́yìn Áhábù bàbá à rẹ nígbà tí Olúwa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀:

26. ‘Ní àná, mo rí ẹ̀jẹ̀ Nábótì pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ni Olúwa wí.’ Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ gbé e sókè, kí o sì jù ú sí orí ilẹ̀ oko náà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa.”

27. Nígbà tí Áhásáyà ọba, Júdà rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Bẹti-Hágánì. Jéhù sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, “Pa á pẹ̀lú!” Wọ́n sá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Gúrì lẹ́bà a Íbíléámù, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Mégídò, ó sì kú síbẹ̀.

28. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbé e pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lọ sí Jérúsálẹ́mù, ó sì sin ín pẹ̀lú, bàbá a rẹ̀ nínú ibojì rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dáfídì.

29. (Ní ọdún kọkànlá ti Jórámù ọmọ Áhábù, Áhásáyà ti di ọba Júdà.)

30. Nígbà náà Jéhù lọ sí Jésérẹ́lì. Nígbà tí Jésébélì gbọ́ nípa rẹ̀, ó kun ojú u rẹ̀, ó to irun rẹ̀, ó sì wò jáde láti ojú fèrèsé.

31. Bí Jéhù ti wọ ẹnu ìlẹ̀kùn, ó béèrè, “Ṣé ìwọ wá lálàáfíà, Símírì, ìwọ olùpa ọ̀gá à rẹ?”

32. Ó gbójú sókè láti wo fèrèsé, ó sì pè jáde, “Ta ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ mi? Ta ni?” Ìwẹ̀fà méjì tàbí mẹ́ta bojú wò ó nílẹ̀.

33. Jéhù sọ wí pé, “Gbé e jùsílẹ̀ wọ́n sì jù ú sílẹ̀!” Díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì fọ́n sí ara ògiri àti àwọn ẹṣin bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn.

34. Jéhù wọ inú ilé lọ, ó jẹ ó sì mu. “Tọ́jú obìnrin yẹn tí a fi bú,” Ó wí, “Kí o sì sin-ín, nítorí ọmọbìnrin ọba ni ó jẹ́.”

Ka pipe ipin 2 Ọba 9