Nígbà tí Jórámù rí Jéhù, ó béèrè pé, “Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà, Jéhù?”“Báwo ni àlàáfíà yóò ṣe wà,” Jéhù dáhùn, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí gbogbo ìbọ̀rìṣà àti iṣẹ́ àjẹ́ ti mọ̀mọ́ rẹ Jésébélì di púpọ̀?”