Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 9:15-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ṣùgbọ́n ọba Jórámù ti padà sí Jéṣérẹ́lì láti lọ sàn nínú ọgbẹ́ tí àwọn ará Árámù ti dá sí i lára nínú ogun pẹ̀lú ọba Hásáélì ti Árámù). Jéhù wí pé, “Tí èyí bá jẹ́ ọ̀nà tí ò ń rò, má ṣe jẹ́ kí ẹnìkankan kí ó yọ jáde nínú ìlú ńlá láti lọ sọ ìròyìn náà ní Jéṣérẹ́lì.”

16. Nígbà náà ó wọ inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì gùn ún lọ sí Jésérẹ́lì, nítorí Jórámù ń sinmi níbẹ̀ àti ọba Áhásáyà tilọ láti lọ wò ó.

17. Nígbà tí olùṣọ́ kan tí ó dúró ní ilé ìṣọ́ ní Jésérẹ́lì, rí ọ̀wọ́-ogun Jéhù tí wọ́n ń súnmọ́ tòsí, ó pè jáde, “Mo rí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó ń bọ̀.”“Mú ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kan,” Jórámù pa á láṣẹ. “Rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wọn kí o sì béèrè pé, ‘Ṣé ẹ̀yin wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”

18. Ọkùnrin ẹlẹ́ṣin náà, lọ láti lọ bá Jéhù ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba wí: ‘Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”“Kí ni ìwọ ní ṣe pẹ̀lú àlàáfíà?” Jéhù sì dáhùn. “Ṣubú sími lẹ́yìn.”Olùṣọ́ náà sì wí fún un pé, “Ìránṣẹ́ náà ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́.”

19. Bẹ́ẹ̀ ni, ọba rán ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kejì, Nígbà náà ó wá sí ọ̀dọ̀ wọn, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba sọ:“Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?” Jéhù dáhùn, “Ṣúbu sími lẹ́yìn.”

20. Olùṣọ́ náà sì fi sùn. “Ó ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́ pẹ̀lú. Wíwá rẹ̀ sì dàbí ti Jéhù ọmọ Nímsì, ó ń wa kẹ̀kẹ́ bí ti aṣiwèrè.”

21. “Fi ìwọ̀ kọ́ kẹ̀kẹ́ ogun mi.” Jórámù pa á láṣẹ. Àti nígbà tí a fi kọ́, Jórámù ọba Ísírẹ́lì àti Áhásáyà ọba Júdà, gun kẹ̀kẹ́ lọ, olúkúlùkù nínú kẹ̀kẹ́ ogun tirẹ̀, láti lọ bá Jéhù. Wọ́n bá a pàdé ní ibi oko tí ó ti jẹ́ ti Nábótì ará Jéṣírẹ́lì.

22. Nígbà tí Jórámù rí Jéhù, ó béèrè pé, “Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà, Jéhù?”“Báwo ni àlàáfíà yóò ṣe wà,” Jéhù dáhùn, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí gbogbo ìbọ̀rìṣà àti iṣẹ́ àjẹ́ ti mọ̀mọ́ rẹ Jésébélì di púpọ̀?”

23. Jórámù yípò padà, ó sì sá lọ ó sì ń pe Áhásáyà, “ó ṣe ìwà àrékérekè, Áhásáyà!”

24. Nígbà náà, Jéhù fa ọrun rẹ̀, ó sì yin Jórámù láàárin èjìká méjèèjì. Ọfà náà sì wọ inú ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú lulẹ̀ láti orí kẹ̀kẹ́ rẹ̀.

25. Jéhù sọ fún Bídíkárì, balógun kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ pé, “Gbé e sókè kí ó sì jù ú sí orí pápá tí ó jẹ́ ti Nábótì ará Jésérẹ́lì. Rantí bí èmi àti ìwọ ti ń gun kẹ̀kẹ́ papọ̀ lẹ́yìn Áhábù bàbá à rẹ nígbà tí Olúwa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀:

26. ‘Ní àná, mo rí ẹ̀jẹ̀ Nábótì pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ni Olúwa wí.’ Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ gbé e sókè, kí o sì jù ú sí orí ilẹ̀ oko náà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa.”

27. Nígbà tí Áhásáyà ọba, Júdà rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Bẹti-Hágánì. Jéhù sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, “Pa á pẹ̀lú!” Wọ́n sá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Gúrì lẹ́bà a Íbíléámù, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Mégídò, ó sì kú síbẹ̀.

28. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbé e pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lọ sí Jérúsálẹ́mù, ó sì sin ín pẹ̀lú, bàbá a rẹ̀ nínú ibojì rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dáfídì.

29. (Ní ọdún kọkànlá ti Jórámù ọmọ Áhábù, Áhásáyà ti di ọba Júdà.)

30. Nígbà náà Jéhù lọ sí Jésérẹ́lì. Nígbà tí Jésébélì gbọ́ nípa rẹ̀, ó kun ojú u rẹ̀, ó to irun rẹ̀, ó sì wò jáde láti ojú fèrèsé.

31. Bí Jéhù ti wọ ẹnu ìlẹ̀kùn, ó béèrè, “Ṣé ìwọ wá lálàáfíà, Símírì, ìwọ olùpa ọ̀gá à rẹ?”

32. Ó gbójú sókè láti wo fèrèsé, ó sì pè jáde, “Ta ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ mi? Ta ni?” Ìwẹ̀fà méjì tàbí mẹ́ta bojú wò ó nílẹ̀.

33. Jéhù sọ wí pé, “Gbé e jùsílẹ̀ wọ́n sì jù ú sílẹ̀!” Díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì fọ́n sí ara ògiri àti àwọn ẹṣin bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn.

Ka pipe ipin 2 Ọba 9