Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 7:15-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Wọ́n sì tẹ̀lé wọn títí dé Jọ́dánì, wọ́n sì rí gbogbo ọ̀nà kún fún agbádá pẹ̀lú ohun èlò tí ará àwọn Ṣíríà gbé sọnù ní yàrá wọn. Ìránsẹ́ náà padà ó sì wá sọ fún ọba.

16. Nígbà náà àwọn ènìyàn jáde lọ ìkógun ní ibùdó àwọn ará Ṣíríà. Bẹ́ẹ̀ ni òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kan ni wọ́n tà fún Sẹ́kẹ́lì kan, àti òsùnwọ̀n báálì méjì ní Ṣékélì kan, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.

17. Nísìn yìí ọba sì mú ìjòyè náà lórí ẹni tí ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ tì ní ìkáwọ́ ẹnu ibodè, àwọn ènìyàn sì tẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ẹnu ibodè. Ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti ṣọ tẹ́lẹ̀ nígbà tí ọba sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀.

18. Ó sì ti sẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyan Ọlọ́run ti ṣọ fún ọba: “Ní àsìkò yìí ní ọ̀la, òsùnwọ̀n ìyẹ̀fun ni a ó ta nì Ṣékélì kan àti òsùnwọ̀n méjì báálì ní Ṣékélì kan ní ẹnu ọ̀nà ibodè Ṣamáríà.”

19. Ìjòyè náà ti wí fún ènìyàn Ọlọ́run pé, “Wò ó, kó dà ti Olúwa bá sí fèrèsé ní ọ̀run, ṣé èyí lè ṣẹlẹ̀?” Ènìyàn Ọlọ́run sì ti dáhùn pé, “kìkì ojú rẹ ni ìwọ yóò fi rí i, Ṣùgbọ́n ìwọ kò ní jẹ ọ̀kan kan lára rẹ̀.”

20. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí fún un gẹ́lẹ́, nítorí tí àwọn ènìyàn tẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ẹnu ibodè, ó sì kú.

Ka pipe ipin 2 Ọba 7