Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 25:6-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Wọ́n sì mú un wọ́n sì mú lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbílà, níbi tí à ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀.

7. Wọ́n sì pa ọmọ Ṣédékáyà níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dèé pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí Bábílónì.

8. Ní ọjọ́ kèje ní oṣù karùn ún, ní ọdún ìkọkàndínlógún ti Nebukadinésárì ọba Bábílónì, Nebukadinéṣárì olórí ẹ̀sọ́ ti ọba ìjòyè ọba Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù

9. ó sì finá sí ilé Olúwa, ilé ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù àti gbogbo ilé pàtàkì, ó jó wọn níná.

10. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Bábílónì, lábẹ́ olórí ti ìjọba ẹ̀sọ́, wó ògiri tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká lulẹ̀.

11. Nebukadinésárí olórí ẹ̀ṣọ́ Kó lọ sí ìgbékùn gbogbo ènìyàn tí ó kù ní ìlú, àti àwọn Ísánsà àti àwọn tí ó ti lo sí ọ̀dọ̀ ọba Bábílón.

12. Ṣùgbọ́n olórí ẹ̀sọ́ fí àwọn talákà ènìyàn ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àti orí pápá.

13. Àwọn ará Bábílónì fọ́ ọwọ́n idẹ sí túútúú, àti ìjòkòó àti agbada ńlá idẹ tí ó wà nílé Olúwa wọ́n sì kọ́ idẹ wọn sí Bábílónì.

14. Wọ́n sì kóo lọ pẹ̀lú àwo ìkòkò ọkọ́, àlùmágàjí fìtílà, síbí àti gbogbo ohun èló idẹ tí wọ́n lò nílé tí wọ́n fi sisẹ́.

15. Olórí ìjọ̀ba ẹ̀sọ́ mu ìfọnná, àti ọpọ́n, èyí tí wọ́n fi wúrà àti Sílifà ṣe lọ.

16. Bàbà méjì láti ara ọ̀wọ̀n òkú àti ìjòkòó, tí Ṣólómónì ti ṣe fún ilé Olúwa, ó ju èyí tí a lé wọ́n lọ.

17. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀wọ̀n gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ ẹsẹ̀ méjìlélógún Olórí Bàbà lórí ọkẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀wọ̀n ọ̀gá ni ìwọ̀n mẹ́rin àti ààbò wọn sì ṣe lọ́sọ́ọ̀ pẹ̀lú iṣe àwọ̀n àti àwọ pòmégránátè tí ó wà lórí ọ̀nà orí gbogbo rẹ̀ yíká, ọ̀wọ̀n mìíràn, pẹ̀lú iṣẹ́ híhun, wọ́n sì kéré.

Ka pipe ipin 2 Ọba 25