Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 25:22-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Nebukadínésárì ọba Bábílónì ó mú Gédalíàh ọmọ Áhíkámù ọmọ ṣáfánì, láti jọba lórí àwọn ènìyàn tí ó ti fa kalẹ̀ lẹ́yìn ní Júdà.

23. Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Bábílónì ti yan Gédálíàh gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gédálíàh ni Mísípà. Ísímáélì ọmọ Nétaníàh, Jóhánánì ọmọ Káréà, Séráíáyà ọmọ Tánhúmétì ará Nétófátì, Jásáníáyà ọmọ ara Mákà, àti àwọn ọkùnrin wọn.

24. Gédálíà sì búrà láti fi dá àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn ìjòyè ará káidéà,” ó wí pé, “Ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì sin ọba Bábílónì, yóò sì dára fún un yín.”

25. Ní oṣù kèje, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, Ísmáélì ọmọ Nétaníáyà, ọmọ Èlísámà, ẹni tí ó jẹ́ ti ẹ̀jẹ̀ ọba, wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá ó sì kọlù Gédálíáyà àti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹwàá ará Júdà àti àwọn ará káídéà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Míspà.

26. Nítorí èyí, gbogbo àwọn ènìyàn láti ẹni kékeré títí dé ẹni ńlá, àti pẹ̀lú àwọn olórí ogun, sá lọ si Éjíbítì nítorí ẹ̀rù àwọn ará Bábílónì.

27. Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí a lé Jéhóíákínì ọba Júdà kúrò nílú, ní ọdún tí Efili-Méródákì di ọba Bábílónì, ó tú Jéhóíákínì kúrò nínú túbú ní ọjọ́ kẹtàdínlógbọ̀n oṣú kéjìlá.

28. Ó sì sọ̀rọ̀ dáradára ó sì fún ún ní ìjòkòó tí ó ga lọ́lá jùlọ ju gbogbo àwọn ọba tó kù tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Bábílónì lọ,

29. Bẹ́ẹ̀ ni Jéhóíákínì fi sí ẹ̀gbẹ́ kan àwọn aṣọ́ túbú àti fún gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ tí ó ku oúnjẹ ó ń jẹ, nígbà gbogbo ní orí tabílì ọba.

30. Ní ojoojúmọ́ ọba fún Jéhóíákínì ní ohun tí ó yọ̀ǹda nígbà kúgbà gẹ́gẹ́ bí ó tí ń bẹ láàyè.

Ka pipe ipin 2 Ọba 25