Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 23:31-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Jéhóáhásì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́talélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Hámútalì ọmọbìnrin Jeremíáyà; ó wá láti Líbínánì.

32. Ó ṣe búburú lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ ti ṣe.

33. Fáráò Nékó sì fi sí inú ìdè ní Ríbílà ní ilẹ̀ Hámátì, kí ó má ba à lè jọba ní Jérúsálẹ́mù. Ó sì tan Júdà jẹ fun iye ìwọ̀n ẹgbẹ̀rin talẹ́ntì wúrà kan.

Ka pipe ipin 2 Ọba 23