Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 15:8-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ní ọdún kejìdínlógójì Ásáríyà ọba Júdà. Ṣakaríà ọmọ Jéróbóámù di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà, ó sì jọba fún oṣù mẹ́fà.

9. Ó ṣe búburú lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ tí ṣe. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá.

10. Ṣálúmù ọmọ Jábésì dìtẹ̀ sí Ṣakaríà. Ó dojúkọ ọ́ níwájú àwọn ènìyàn, ó sì pa á, ó sì jọba dípò rẹ̀.

11. Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Ṣakaríà. Wọ́n kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì.

12. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ fún Jéhù jẹ́ ìmúṣẹ: “Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì títí dé ìran kẹrin.”

13. Ṣálúmù ọmọ Jábésì di ọba ní ọdún kọkàndínlógójì Ùsáyà ọba Júdà, ó sì jọba ní Ṣamáríà fún oṣù kan.

14. Nígbà náà Ménáhémù ọmọ Gádì lọ láti Tírísà sí Ṣamáríà. Ó dojúkọ Ṣalúmù ọmọ Jábésì ní Samáríà, ó pa á ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Ka pipe ipin 2 Ọba 15