Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 15:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n tí Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, Ásáríyà ọmọ Ámásáyà ọba Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba.

2. Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rindínlógún nígbà tí o di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjìléláàdọ́ta. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a má a jẹ́ Jékólíà; ó wá láti Jérúsálẹ́mù.

3. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Ámásáyà ti ṣe.

4. Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí wọn kúrò; Àwọn ènìyàn náà tẹ̀ṣíwájú láti máa rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀.

5. Olúwa sì kọlu ọba náà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀, títí di ọjọ́ tí ó kú, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀tọ̀. Jótamì, ọmọ ọba sì tọ́jú ààfin, ó sì ń darí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.

6. Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Ásáríyà, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà.

7. Ásáríyà sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. A sì sin ín sí ẹ̀bá wọn ní ìlú ńlá ti Dáfídì. Jótamì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

8. Ní ọdún kejìdínlógójì Ásáríyà ọba Júdà. Ṣakaríà ọmọ Jéróbóámù di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà, ó sì jọba fún oṣù mẹ́fà.

9. Ó ṣe búburú lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ tí ṣe. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá.

Ka pipe ipin 2 Ọba 15